You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Daddys Showkey sí Naira Marley: Mi ò gbè lẹ́yìn Naira Mailey fún ìwà ìbàjẹ́
Gbajugbaja olorin reggae lorilẹede Naijiria ti gbogbo eniyan mọ siDaddyshokey ti ni oun ko fayegba iwa ibajẹ lawujọ ati wi pe oun ko le lọwọ si.
Naira Mailey sọ eyi loju opo ikansiraẹni Instagram lẹyin ti awọn eniyan bu ẹnu atẹ lu ọrọ to sọ lori igbesẹ ajọ EFCC lasiko ti wọn gbe lọ si ile ẹjọ lori ẹsun lilo gbajuẹ fi gba owo lọwọ awọn eniyan to ba ko si ọwọ ẹ.
Daddyshokey ni iwa ibajẹ wọpọ lawujo wa, amọ ko ye ki EFCC lo aduru eso alaabo to po to bẹ ẹ lati mu ọdọ ti fẹsun asemase kan lọ si ile ẹjọ.
Gbajugbaja olorin Reggae naa wa kesi ajọ EFCC lati jẹ ki aanu ijọba lori idajọ lori ọrọ Naira Mailey.
Ti a ko ba gbagbe, Daddyshokey laipẹ yii ke si ajọ lati fi Naira Mailey lọrun silẹ nitori wi pe oun kọ lo n pa awọn eniyan lorilẹede Naijiria tabi ju ado oloro.