You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP vs Tinubu: Aṣíwájú Tinubu lọ́ra láti fi wá kọ́ èébú
Ẹgbẹ oselu PDP ti ke si adari ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Aṣiwaju Ahmed Tinubu lati tọwọ ọmọ rẹ bọṣọ lori bi o ṣe n tẹnu bọlẹ lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ni oju opo ikansiraẹni Twitter wọn, PDP ni aṣiwaju n fi awọn kọ eebu pẹlu bi o ṣe gbẹra lati orilẹede Naijiria lọ si Mecca lati lọ ba Aarẹ Buhari sọrọ kubakungbe.
PDP bu ẹnu atẹ lu Asiwaju Tinubu pe o fẹsun kan ẹgbẹ oselu PDP ati oludije sipo aarẹ lẹgbe oselu naa, Atiku Abubakar wi pe wọn fẹ fi tipatipa gbe e wọle gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni wọn ke si ẹgbẹ oselu APC wi pe ki o ba adari rẹ sọrọ ko ye tẹnubọlẹ kiri mọ gẹgẹ bi agba.