You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo marijuana: Naijiria kò fẹsẹ̀rinlẹ̀ tó láti gba igbó láàyè fún ìtọ́jú àìsàn- Onímọ̀ ìlera
Dokita to n ṣe itọju ọpọlọ Raliat Akerele ti ṣe ikilọ wi pe wahala yoo bẹ silẹ ni Naijiria ti Ipinlẹ Ondo ba bẹrẹ si ni gbin igbo ti igbo naa si di oun ti ofin gba laaye ni orilẹee yii.
Dokita Akerele ni ti ijọba ba gba awọn eniyan laaye lati maa lo igbo, ilokulo oogun ni yoo mu wa ti yoo si jẹ ki aarun ọpọlọ wọ pọ. O ni eyi yoo si tun mu airiṣẹṣe àti airílégbé dání.
Ọrọ yi jẹyọ lẹyin ti adari ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun Mustapha Abdallah ati gomina Ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu, Ọgá NDLEA lọ kọ nípa gbíngbin igbó ní Thailand fun lilo gẹgẹ bi oogun.
Dokita Akerele ni bo tilẹ jẹ pe lilo igbo gẹgẹ bii oogun dara, abojuto ọrọ oogun lilo ni orilẹede Naijiria ko dara to.
O sọ fun BBC wipe ti wọn ba bẹrẹ si ni gbin igbo ni Ipinlẹ Ondo ti ijọba si gba a laye labẹ ofin, alaisan yoo le wọ ile itaja oogun lati ra igbo gẹgẹ bi oogun lai ni iwe dokita lọwọ nitori abojuto oogun lilo ko fẹṣerinlẹ to.
Dokita Akerele to n ṣiṣẹ gẹgẹ bii oluwosan ọpọlọ ni ile iwosan ọpọlọ ti iijọba apapọ to wa ni Yaba ni Ipinlẹ Eko ni ọpọlọpọ awọn dokita bi ti oun ko fọwọ si lilo igbo gẹgẹ bii oogun nitori wipe o le fa awọn aisan ọpọlọ oriṣiriṣi.
O tun fi kun wipe ni ọgba ile iwosan ọpọlọ to wa ni Yaba, ọpọlọpọ alaisan to wa nibẹ, igbo mimu lo da ori wọn ru.
Ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun ni asiko ko ti to
Bakan naa, ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria ti ni asiko ko ti i to fun gbigba igbo lilo laaye labẹ ofin .
Adari ẹgbẹ naa ni Naijiria, Dokita Francis Faduyile ni ofin to de awọn ilokulo oogun ni orilẹede Naijiria ko fẹsẹrinlẹ to nitori wipe awọn alaṣe ko ṣiṣẹ wọn to, eyi to fa ti ọpọlọpọ ṣe n ṣi oogun lo.
Lọwọlọwọ yii, igbo mimu ṣi lodi sofin ni Naijiria, ati wipe ẹnikẹni ti ọwọ ba ba le lọ ẹwọn.