Onnoghen: Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ẹjọ́ náà kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ìlú Abuja ti da ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí adájọ́ àgbà Naijiria tẹ́lẹ̀rí, Walter Onnoghen pè láti tako aṣẹ idaniduro ranpẹ̀ ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ibajẹ ati aṣemaṣe awọn to di ipo ilu mu, CCT pa to yọọ niṣẹ́ ni Ọjọ Kẹtalelogun, Ọdun 2019 saaju igbẹjọ rẹ.

Gẹgẹ bi idajọ ti ijoko ẹlẹnimẹta ti Adajọ Stephen Adah ṣe adari rẹ pa, ile ẹjọ kòtẹ́milọ́rùn ni aṣẹ idaniduro ranpẹ̀ ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ibajẹ ati aṣemaṣe awọn to di ipo ilu mu, CCT pa, lodi si ẹtọ Onnoghen labẹ ofin.

Adajọ Stephen Adah nigbati o n ka idajọ naa mẹnu ba pe ko yẹ ki igbẹjọ naa waye pẹlu ifunrasi ati ọna aitọ ti awọn olupẹjọ fi gba aṣẹ idaniduro ranpẹ.

Sibẹsibẹ, o da ẹjọ naa nu nitori ile ẹjọ CCT ti pari igbẹjọ naa eyi to gbe idalẹbi fun adájọ́ àgbà Naijiria tẹ́lẹ̀rí naa.

Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu aṣẹ idaniduro ranpẹ̀ yọ Onnoghen kuro niṣẹ ni Ọjọ Kẹtalelogun, Ọdun 2019.