You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo Regent: Ó dùn mí pé mi ò lè wọ aṣọ obìnrin mọ́ gẹ́gẹ́ bí adelé ọba
Adele Ọba ti ìlú Aaye, ìjọba ibilẹ Ifẹdọrẹ ní ìpínlẹ̀ Ondo, Ọmọbabinrin Taiwo Oyebola Agbona jẹ lẹyin ti baba rẹ papoda ni ọdun kan o le sẹyin.
Aṣa ati iṣe ilu ni wọ́n tẹlé ti wọn fi yan an gẹgẹ bii adele nitori oun ni akọbi baba rẹ.
Ẹwẹ, Ọmọbabinrin Taiwo ni bi ọrọ tabi iṣẹlẹ ba waye, atoun atawọn oloye lawọn yoo jokoo gbe e yẹwo lati wo ohun to dara lati ṣe, o ni ijọba oun kii ṣe bii eyi ọba a ṣaa maa ba lori ohun gbogbo gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sọ.
Ó ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gboye bayii ninu imọ Medical Laboratory Science (Heamatology) ṣùgbọ́n ipele ikarun lo ṣi wa ti ifa yan an lati wa jẹ adele Ọba ilu rẹ.
Lara awọn èèwọ̀ rẹ gẹgẹ bi Ọba ree:
Ko gbudọ kunlẹ ki ẹnikẹni koda ko jẹ iya rẹ.
Ko gbudọ jẹun nita gbangba loju gbogbo eniyan.
Ko le lanfani ati maa mura bii obinrin nipo adele Ọba.