You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
#BBCGOVDEBATE: ADC fẹ́ tún ìpínlẹ̀ Ọyọ ṣe ní kíákíá -Olufemi Lanlehin
Solagbade Olufemi Lanlehin to n dije dupo gomina ni ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe awọn ti ṣetan lati tun ipinlẹ Ọyọ ṣe ni kiakia.
Lanleyin to jẹ agbẹjọrọ ati oloṣelu ti fi igba kan ṣe sẹnetọ fun Iwọ Guusu ni ipinlẹ Ọyo ni Ile Igbimọ Asofin Agba ni ọdun 2011 si 2015.
Ile Iwe Ibadan Grammar School ni ilu Ibadan ati ile iwe girama Igbobi College ni ilu Eko.
Nkan marun-un to yẹ ki ẹ mọ nipa Olufẹmi Lanlẹhin
- Onimọ nipa eto ofin ni Lanlehin ni ile iwe giga fasiti ti Nigeria ni Nsukka ni ọdun 1977.
- Ni ọdun 2011 ni Sẹneto Lanlehin soju Guusu Ọyọ labẹ ẹgbẹ oselu Action Congress of Nigeria.
- Ni ọdun 2014, Lanlehin darapọ mọ ẹgbẹ oselu Accord Party lẹyin ti ẹgbẹ oselu ACN darapọ mọ ẹgbẹ oselu miran lati da ẹgbẹ oselu APC silẹ.
Lanlẹhin dibo mii ti ko wọle ninu rẹ.
- Amọ ninu idibo gbogboogbo ọdun 2015 ni Lanlehin ti kuna fun Sẹnetọ Adesoji ti ẹgbẹ oselu APC fun ipo sẹnetọ Guusu Ọyọ.
- Ni bayii, Lanlẹhin lo n dije fun ipo gomina ninu idibo gbogboogbo to nbọ ni Osu kẹta, ọdun 2019 yii labẹ ẹgbẹ oselu ADC ni ipinlẹ naa.