You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Banky W: Ọkàn Adesuwa, ìyàwó mi kò balẹ̀ nítorí mo kánlu agbami òṣèlú
Ṣe ẹ ranti gbajugba olorin takasufe ni, Banky W.?
Ṣe ẹ si mọ pe oun naa fẹ dije fun ipo oṣelu ninu saa idibo apapọ ti o n bọ lọọọkan yii? Bẹẹni, Banky W. fẹ dije fun ipo aṣoju-ṣofin nileegbimọ aṣofin apapọ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Modern Democratic Party.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọṣa iroyin to jẹ tuntun lori igbesẹ ati dije rẹ bayii ni pe, Banky W. tin parọwa ẹbẹ iranwọ owo ranṣẹ sawọn ololufẹ rẹ.
Lori opo ayelujara twitter ati instagram rẹ lo fi ẹbẹ iranwọ owo naa si.
O ni bi eto idibo ṣe n sun mọle di bii ọsẹ mẹfa bayii, yoo di dandan fun oun ati ikọ ipolongo oun lati gunle ipolongo olojule-dojule ninu eyi ti wọn yoo ti nilo awọn patako alakọle (billboards), akoko lati kede lori redio ati mohunmaworan pẹlu ori ẹrọ ayelujara naa, owo si ni yoo jẹ.
O ni iranwọ owo latọdọ awọn ololufẹ oun yoo ṣe pupọ ninu ọrọ ipolongo idibo oun naa.
Bakan naa lo sọrọ lori bi ọkan iyawo rẹ Adesuwa ko ṣe balẹ lati igba ti oun ti kede ati kan lu agbami oṣelu.
O ni iwa aitọ gbogbo eyi to kun agbo oṣelu lo n ba iyawo oun lẹru 'ki wọn ma baa ṣe oun ni ijamba tabi ta epo si ala oun.'