2019 Elections: Àwọn olùdíje ipò Gómìnà ní Kwara yóò sọ ààtò wọn
Gẹgẹ bi akitiyan ile iṣẹ iroyin BBC Yoruba lati mu iroyin nipa idibo orilẹede Naijiria lọdun 2019 wa fun gbogbo eniyan nile ati lẹyin odi, ipade itagbangba yoo waye lawọn ipinlẹ kọọkan nilẹ Yoruba.
Ibi ti wọn yoo ti ṣide ipade itagbangba ti ọdun 2019 ni ipinlẹ̀ Kwara eyi ti yoo waye ni ọjọ kẹwaa, oṣu kinni ọdun 2019.
Deede agogo mẹsan owurọ ni eto yoo bẹrẹ pẹlu bi awọn akopa yoo ṣe ti ṣaaju fi orukọ silẹ loju opo https://bit.ly/2rHOXzO eyi ti BBC Yoruba ti pese.