Osun Election 2018: 'Ojú ọ̀dọ́ nipinlẹ̀ Ọṣun ti la'

Àkọlé fídíò, Osun Election 2018: 'Ojú ọ̀dọ́ nipinlẹ̀ Ọṣun ti la'

BBC Yorùbá jáde fọrọ wa àwọn ọ̀dọ́ ati obinrin ipinlẹ Oṣun lẹnu wò.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lo sọ pé àwọn ti ṣetan lati jade lọ dibo fun ẹni to wu awọn lati rọ́pò gomina Arẹgbẹṣọla.

Gomina Arẹgbẹṣọla lo ti tukọ ipinlẹ Ọṣun fun ọdun mẹjọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC titi di asiko yii.

Awọn Oludije mejidinlaadọta ni ajọ eleto idibo INEC gbe orukọ wọn sita pe wọn n dupo gomina Ọṣun.

Awọn agbofinro loriṣii ti kun ipinlẹ Ọṣun lati rii pe ohun gbogbo lọ nirọwọrọsẹ.