Osun Election 2018: Aráàlú ní àwọn kò fẹ́ ìjọba elébi mọ́
BBC Yoruba bọ sigboro lati mọ ìgbaradì àwọn eeyan ipinlẹ Ọsun nipa eto idibo ti yoo waye lọjọ Abamẹta ati irufẹ ijọba ti wọn n reti pe ko gba akoso ipinlẹ naa.
Ọpọ awọn eeyan to ba wa sọrọ lo ni ijọba ti yoo fi ọkan awọn balẹ, ti awọn osisẹ yoo ri owo osu wọn gba deede ati eyi ti yoo mu ki ilu dẹrọ lawọn n foju sọna fun.