Ọṣun Decides:'Màá san gbogbo owó oṣù òṣìṣẹ́ lékunréré'-Akinbade

Àkọlé fídíò, Ọṣun Decides:'Màá san gbogbo owó oṣù òṣìṣẹ́ lékunréré'-Akinbade

Akinbade ni òun kò gbàgbọ́ nínú ìdajì owó oṣù.

Alhaji Fatai Akinbade jẹ́ ọkan lára àwọn ti BBC Yorùbá pè sipade ita gbangba ti a ṣe lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan an ni gbọngan Olagunsoye Oyinlọla ni Fasiti ipinlẹ Ọṣun.

Oludije mejidinlaadọta ni ajọ eleto idibo INEC gbe orukọ wọn sita gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ọṣun bayii.

Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC yii ni oun gbagbọ pe orí kan kò ju ikeji lọ nipinlẹ Ọṣun fún ìdí eyi, iwọ oorun Ọṣun ni gomina tuntun kan lasiko yii.

Alhaji Fatai Akinbade ni owọ tijọba Ọṣun fi n ṣofo lasiko yii to ìdá ọgọrin ninu ọgọrun un ni eyi ti oun a fopin si ti oun ba wọle.

O ṣalaye ipinnu rẹ fawọn eniyan ipinlẹ Ọṣun ni ẹkunrẹrẹ.