Osun Decides: Adegoke ni òun kò ni lo kọngilá mọ́ nipinlẹ Ọṣun

Alfred Adegoke lo n dije labẹ ẹgbẹ òṣèlú 'Socialist Party of Nigeria' nipinlẹ Ọṣun.

O sọrọ lori awọn nkan to ni lọkan lati ṣe fun ipinlẹ Ọṣun ti o ba jawe olubori ninu eto idibo fun ipo gomina to m bọ lọjo kejilelogun, oṣu kẹsan an yii.

O fi àwọn oniṣẹ ọwọ́ lọkan balẹ pe gbogbo wọn loun maa gbe iṣẹ àgbàṣe fun lati tun gbogbo ọna Awolowọ atijọ ṣe.

Alfred ni ti wọn ba dibo fun oun gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun, oun ko ni fọwọ kan owo nina fun eto aabo (security vote) rara.