Ikú Arẹwa: Ìdíje omidan to rẹwà jùlọ ló fẹ́ kopa nínú rẹ̀

Ikú ogun wọn, ni òhun ló ń pa akíkanju, akopa ìdíje arẹwà kan ló jẹ́ Ọọ́run nípè lásìukò t lọ ya fótò ní eti òkun ti wọn ń pè ni Oasis Beach.

Ọmọbinrin náà jẹ́ ọkan lára àwọn akópa nínú idije oge Fasiti Ghana. Wọn ti wà lórí àpáta tipẹ ti wọn ń ya foto nígbà ti ìjì bẹ̀rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan nínú àwọn ọmọbinrin náà ti di àwáti nígbàti àwọn méjì míràn àtí ọkunrin Kan ṣì wà ní ilé ìwòsàn ni Cape coast.

Ọmọbinrin tó kú àti èyí tí ó dàwátì ní wọn pè ni ọmọ Fasiti Ghana ẹ̀ka Mampong.

Adari ètò ilé ẹkọ náà ajagun fẹyìnti Baah Bentum sọ pé, àwoọn ọmọbinrin náà ń kópa nínú ìdíje ọmọbinrin to rẹwà jù ní Fasiti Ghana