Yomi Shogunlẹ: Ọ̀rẹ́kùnrin Yahoo Yahoo ló fi Khadijat Olubọyọ ṣe ògùn owó

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Igbákejì kọmíṣánà Ọlọ́pàá, Yọmi Shogunlẹ ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ ikú ọmọ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo tẹ́lẹ̀rí naa gba àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní ìmọ̀ràn lójú òpó Twitter rẹ̀ pé kí wọ́n mase dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ Yahoo Yahoo.

Isẹlẹ banujẹ lo waye ni ile Igbakeji Gomina Ipinle Ondo tẹlẹri, Alhaji Lasisi Olubọyọ, nigbati wọn ba oku ọmọ rẹ, khadijat ni ile ọrẹkunrin rẹ, Adeyemi Alao ni Akure, ní ipinlẹ Ondo, lẹyin ti wọn ti n wa ọdọbinrin naa lati bi osẹ diẹ sẹhin.

Igbákejì kọmíṣánà Ọlọ́pàá, Yọmi Shogunlẹ nigba ti oun fesi si isẹlẹ ni oju opò Twitter rẹ ní, okú ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ ìpele àṣekágbá ní fásitì náà ti ń dí ìbajẹ́ lábẹ́ ìbùsùn ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, tó ní ó jẹ́ jàgùdà orí ẹ̀rọ ayélujára, tí gbogbo ènìyàn ń pè ní Yahoo Yahoo.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà náà kò dákẹ́ bí ó ti lẹ jẹ́ pé wọ́n ń dárò ọdọbinrin naa, lọ́gán ni wọ́n fun Yọmi Shogunlẹ lesi ni oju opo Twitter rẹ.

Agbẹnusọ ile isẹ ọlọpa ni ipinlẹ Ondo, Femi Joseph to fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba sọ wi pe, isẹlẹ naa jẹ oun ibanujẹ fun awọn obi arabinrin to jẹ akẹẹkọ ipele asekagba (400 level) ni fasiti, ko to di wi pe o papoda.