Waris Kareem: Emmanuel Macron kan sáárá lórí àwòrán tó yà
Ààrẹ orílẹ̀èdè Faranse, Emmanuel Macron ti gbé oríyìn fún ọmọkùnrin, ẹni ọdún mọ́kànlá kan, Waris Kareem, tó ya àwórán ààrẹ náà, tó sì ń gbé e fún un ní Africa Shrine.
Waris kò fi àkókò sòfò rara ní kété tí ààrẹ Faranse de ibùdó ìgbafẹ́ Afrika Shrine ti olóògbé Fela tó wà nílu Eko, láàrin wákàtí kan sí méjì péré ló ti yà àwòran Macron.
Waris náà jokoo fẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Gómìnà Akinwunmi Ambọde àti gbaju-gbaja olorin nni, Banky W, lati ya foto nibi toti n gbe aworan naa kalẹ fun Emmanuel Macron.