Ọ̀ọ̀ni Ilé Ifẹ̀ kéde Bahia gẹ́gẹ́ bíi olú ìlú Yorùbá lẹ́kùn Amẹ́ríkà

Ọọni ti ile ifẹ, Adeyẹye ogunwusi Ọjaja keji ti kede ilu Bahia lorilẹede Brazil gẹgẹ bii olu ilu ilẹ Yoruba ni agbegbe Amẹrika.

Lasiko ti Ọọni Ogunwusi ṣe abẹwo si ile ijọsin ẹsin abalaye to pẹ ju niha awọn orilẹede Amẹrika, eleyi to jẹ ti awọn alawọ dudu ni ilu Salavador ni ipinlẹ Bahia ni o ṣe ikede yii.

Ọọni ile ifẹ pẹlu awọn ọbalaye mẹtadinlogun lati ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria ati ipinlẹ Kwara, pẹlawọn ọjọgbọn ile ẹkọ giga fasiti wa lorilẹede Brazil bayii fun abẹwo nibẹ.

Ile ijọsin ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Espaco Cultural Da Barroquinha ni Kọmiṣọna fun ọrọ to kan ilẹ Afirika nibẹ Arany Santa ṣalaye pe wọn da a silẹ ni nkan bii ẹgbẹta ọdun sẹyin latọwọ awọn ọmọ ilẹ Afirika ti wọn tẹdo sibẹ.

O ni tẹlẹri, ile ijọsin aguda ni ibẹ ki awọn alawọ dudu to tẹwọ gbaa gẹgẹ bii ile ijọsin fun awọn ẹlẹsin abalaye.

Ninu ọrọ to ba wọn sọ, Ọọni ile ifẹ, Adeyẹye Ogunwusi ni ki oun to gbera kuro ni ile ifẹ ni oun ti ba awọn alalẹ ilẹ Yoruba sọrọ ti wọn si ti fi da oun loju pe nnkan yoo ṣe ẹnuure fawọn eeyan agbegbe naa ni kete ti oun ba ti da ẹsẹ tẹ ibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

" Mo gboriyin fun yin fun bi ẹ ṣe di ẹsin, aṣa ati iṣẹṣe Yoruba mu ti ẹ ko jẹ ki ina rẹ jo ajorẹyinlẹyin ọpọ ọdun ti sababi gbe yin kuro ni ilẹ baba yin.

Mo fẹ ki ẹ maa ṣe itọju awọn obinrin ati ọmọde laarin yin gidi gan an ni. Ti ẹnyin ti ẹ n gbe lokeere ba lee maa gbe ninu ifẹ inu mi yoo dun, n o si lee fi ẹdọ lori oronro."

Lẹyin eyi ni Ọọni ile ifẹ ati alamojuto ijọba Salavador, ACM Neto wa ti ọwọ bọ iwe adehun eleyi ti wọn fi gbe ipo olu ilu awọn ọmọ Yoruba lagbegbe Amẹrika lee ilu Bahia lori.