Abimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?

Àkọlé fídíò, Abimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?

'Mo bú sẹ́kún nígbà tí Davido fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí mi'

Abimbọla Kazeem, to jẹ́ orísun àwàdà to bí àṣà 'ṣé o mọ age mi ni?' tuntun tó ń lọ nigboro sọ fun BBC Yorùbá pé Ìforítì lẹnu iṣẹ́ ti òun yàn láàyò ló gbé òun sókè yìí.

O ni òun ti ṣe ọpọlọpọ àwàdà sẹyin ti kò jẹ itẹwógba rara, bakan naa ni òun ti ṣere ori ìtàgé pẹlu fíìmù ti òun tún ti fi orin kikọ kun àwàdà ṣugbọn pàbó lo ja si.

Kazeem ni àsìkò ló tó ti àdúrà òun fi gba pélu pe òun ko dẹ́kun ìgbìyànjú lẹnu iṣẹ ti orí rán òun.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bayii, 'ṣe o mọ age mi?' ti di eyi ti àwọn eekan bii Davido, D Banj, Iyabọ Ojo, Ọga Bello, Femi Adebayọ atawọn mii ti sọ di nla.

Ìmòràn fún gbogbo ènìyàn ni pe ki onikaluku tẹsiwaju lẹnu iṣẹ òòjọ́ rẹ, lọjọ kan, o maa bi èso ti ò ń fẹ si rere.

Yorùbá gbà pé ìpò làgbà, ki ẹnikẹni rọra jà lọrí ọrọ ọjọ́ orí.