Aṣojúdìbò 51 ló kú ṣáájú ìbò APC l'Ékìtì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Eto idibo lati yan oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ti pari, esi si ti jade ṣugbọn awọn aṣoju-dibo mọkanlelaadọtan ni wọn ti ku ṣaaju ki idibo naa to waye lọjọ abamẹta ni ilu Ado Ekiti.

Igbimọ alakoso ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ekiti lo gbe orukọ awọn eeyan naa jade lori ikanni twitter wọn.

Ẹgbẹrun meji o le ẹgbẹta ati mejidinlogun ni awọn aṣojudibo to yẹ ko dibo nibi eto idibo naa, ṣugbọn igbimọ to ṣe kokari e4to naa labẹ alaga Gomina Al-Makura ni ẹgbẹrun meji ati igba o le mẹtadinlọgbọn ni wọn ṣe ayẹwo fun wọle.

Iwe orukọ awọn aṣojudibo to ku ṣaaju ọjọ idibo eleyi ti alaga ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Jide Awẹ fi sita fihan pe lara awọn to ku naa ni oluyẹwe owo ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Iyabọ babatunde pẹlu ọkan lara awọn igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu naa Amofin bamitẹkọ wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: