AfricanDrumFestival: Abẹ́òkúta gbàlejò èrò fún àjọ̀dùn ìlù

Ayẹyẹ àjọ̀dùn ìlù nílẹ̀ Áfíríkà ti bẹ̀rẹ̀ nílú Abẹ́òkúta.

Nibi ayẹyẹ yii ni wọn ti maa n ṣe afihan ọkan o jọkan ilu iṣẹmbaye ati aṣa ilẹ Yoruba ati gbogbo Afirika.

Ninu ọrọ ti wọn sọ nibẹ, awọn eekan ọbalaye meji nilẹ Yoruba, Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja II ati Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi III gba awọn to wa nipo aṣẹ lẹka iṣejọba gbogbo niyanju lati rii wi pe wọn n ṣe koriya fun igbedide aṣa ilẹ Yoruba.

Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ni idunnu nla lo jẹ fun awọn ọbalaye lasiko yii lati rii pe ajinde n de ba awọn aṣa ilẹ Yoruba.

" Ọpọ àṣà ilẹ kaarọ oojiire ni o ti n lọ, ṣugbọn a dupẹ fun awọn ti Ọlọrun nlo lati gbee soke pada. Kani a mọ pataki idagbasoke aṣa si idagbasoke eto ọrọ aje wa, a o tẹpa mọ .

Aṣa lo n siwaju ẹsin nitori aṣa lagbara ju ẹsin lọ. Ilẹ kaarọ oojiire ni awokọṣe fun gbogbo agbaye.''

Ninu ọrọ tirẹ, Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi ṣalaye pe 'aṣa jẹ ọna kan gboogi lati ṣe aato ilu. Ti a ba mu aṣa wa, a lee ko ilẹ Afirika jọ tii a o si fun wọn ni iwuri lati fi imọ ṣọkan.'

Ni tirẹ, gbajugbaja onkọwe ni, ọjọgbọn Wọle Soyinka rọ awọn ọba alaye lati maṣe kaarẹ lori awọn oloṣelu to n ṣakoso ijọba bayii nipa gbigbawọn lamọran latigba de igba paapaa julọ lori idagbasoke aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.

Ninu ọrọ tirẹ,Aarẹ Muhammadu Buhari ti minisita fun eto iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammed ṣoju fun ni iṣejọba to wa lode bayii ṣetan lati lo anfani to soodo si ẹka aṣa fun igbeleke ọrọ aje awọn eeyan orilẹede naijiria.

Minisita feto iroyin ati aṣa gboriyin fun awọn to gbe ayẹyẹ naa kalẹ pẹlu ileri atilẹyin ijọba apapọ fun ijọba ipinlẹ Ogun lori ajọdun naa.