You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Idibo 2019: Awọn ọdọ sewọde nilu Abuja
Nse ni ẹnu ko gba iroyin loni nilu Abuja, tii se olu ilu Naijira nigbati ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọdọ ya bo ile ijọba nilu Abuja lati fi ẹhonu wọn han.
Awọn ọdọ naa, ti wọn pọ niye lo n fapa janu pe aarẹ Muhammadu Buhari ko tii buwọlu ofin ti yoo faaye gba awọn ọdọ lati maa se ijọba.
Eyi kii si se igba akọkọ tawọn ọdọ yoo ya si igboro lati fi ero wọn han nitori bi ofin yii ko se tii di ohun, bakanaa ni wọn fi ẹhonu han lori ọrọ yii losu keje ọdun 2017.
A gbọ pe yoo to ipinlẹ bii ọgbọn tawọn ọdọ naa ti wa silu Abuja lati wa fi to ijọba leti pe awọn ko kere lati gba akoso orilẹede yii.
Nigba to nsalaye ohun tawọn ọdọ yii ri, ti wọn se nfapa janu, ẹni to nse agbatẹru iwọde naa, tii tun se asofin to nsoju ẹkun idibo Oshodi/Isọlọ nile asoju-sofin ilẹ wa, tii tun se ọmọ bibi ipinlẹ Imo, Hon Tony Nwulu ni awọn nfẹ ki Buhari fontẹ lu ofin ẹ jẹ kọmọde sejọba.
Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:
Nwulu, ẹni to tun fẹ dije gẹgẹ bii gomina nipinlẹ Imo, lo nlewaju ogunlọgọ awọn ọdọ yii, atawọn eeyan to ni ipenija ara ninu iwọde alaafia.
Ofin ẹ jẹ kọmọde sejọba yii si ni ipinlẹ bii ogun ti fontẹ lu jakejado orilẹede yii.