Asoju ijọba Naijiria miran titun de Dapchi, nipinlẹ Yobe

Oríṣun àwòrán, @FMICNigeria
Ijọba apapọ Naijiria titun yan minisita fun iroyin, Lai Mohammed, ati minisita fun ọrọ abẹle, Abdurrahman Dambazau, lọ si Dapchi nitori awọn akẹkọbirin ti wọn sọnu.
Awọn minisita naa wọn yoo ba awọn alase ipinlẹ, awọn ologun ati alase ile-iwe girama Dabchi jiroro lori ona ati ri awọn akẹkọbirin ti wọn di awati lẹyin ikọlu Boko Haram.
Eleyi n waye ni lẹyin igbati awọn obi l'abule Dapchi gbe orukọ akẹkọbirin marunlelogorun jade gẹgẹbi awọn akẹkọ ti wọn sọnu lati alẹ ọjọ Ajẹ.
Ijọba ipinlẹ Yobe kọkọ kede wipe awọn ologun ti gba awọn akẹkọbirin na silẹ.
Sugbọ wọn toro aforoji lẹyin-ọrẹyin wipe iroyin tawọn gbekẹle ti wọn fi sekede naa ki se otitọ.

Oríṣun àwòrán, @MICNigeria
Awọn obi awọn ọmọ naa n foya ki ọrọ naa ma di ọrọ awọn ọmọbirin Chibok ti Boko Haram ji gbe lati ọdun 2014 di asiko yii.
Awọn iroyin ti ẹ le nifẹsi:








