You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ijamba: Ẹmi akẹkọ mọkanlelogun,olukọ meji bọ ni Kano
Awọn ọmọ ileewe girama mọkanlelogun ati olukọ meji ni wọn ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba mọto kan to waye lorilẹede Naijiria.
Gẹgẹbi iroyin se sọ, awọn ọmọ ileewe yii atawọn olukọ wọn n rin irin ajo ifinimọlu lọ si ilu kano, lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria lati ilu Misau, to wa lagbegbe ila oorun ariwa orilẹede yi, nigba ti ijamba naa sẹlẹ.
Iroyin sọ wipe akẹkọ ati olukọ ileewe girama ilu Misau lawọn to lugbadi ijamba mọto naa.
Ajọ ẹsọ oju popo nipinlẹ Kano ati awọn alakoso ileewe girama naa salaye fun BBC wipe, isẹlẹ buruku yii sẹlẹ nigbati ọkọ bọọsi akero ti wọn wọ ati ọkọ nla kan kọlu ara wọn.
Oju ẹsẹ ni gbogbo awọn to wa ninu ijamba ọkọ naa ti gb'ẹmi mi.
Olukọ kan ati akẹkọ kansoso ni ori ko yọ ninu ijamba mọto naa.