Babachir:Lẹta Ọbasanjọ lo bi atimọle fun akọwe ijọba tẹlẹ naa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Niwọn igba to pe oun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọju si ẹlomin bii ilu gangan, eyi lo mu ki ero awọn ọmọ orilẹede yi sọtọọtọ lori bi ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede yi, se nawọ gan akọwe ijọba apapọ ilẹ yi tẹlẹ, Babachir Lawal lana, ti wọn si ju si ahamọ lori ẹsun pe o se magomago owo toto miliọnu lọna ojilerugba ati mẹta naira, eyiti wọn ni awọn nse iwadi le lori.

Bẹẹ ba gbagbe, aarẹ Muhammadu Buhari lo ti kọkọ juwe ọna ile fun akọwe ijọba tẹlẹ naa lori ẹsun iwa ijẹkujẹ to nii se pẹlu gbigbe isẹ agbase sita lọna aitọ, ti igbimọ oluwadi ti ileesẹ aarẹ gbe kalẹ, lọdun to kọja, eyiti igbakeji aarẹ, Yẹmi Ọsinbajo ko sodi, si daba pe igbimọ ti Babachirl Lawal ko sodi to wa fun atunse ẹkun ila oorun ariwa ilẹ yi, ni ẹjọ lati jẹ.

Amọ lati ọdun to kọja, ti igbimọ Ọsinbajo naa ti gbe abọ rẹ kalẹ, ijọba ko ya si ọrọ yi, sugbọn ajs EFCC gbe Babachir Lawal lẹyin wakati mẹrinlelogun pere, ti aarẹ ana nilẹ wa, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ kọwe ransẹ si aarẹ orilẹede yi, Muhammadu Buhari pe ko mase beere fun ibo awọn ọmọ ilẹ yi lati se saa keji lori aleefa nitori ọpọ kudiẹkudiẹ to n waye ninu isejọba rẹ, ninu eyi taa ti ri iwa ajẹbanu to n waye laarin awọn amugbalẹgbẹ rẹ, eyiti wọn n dasọ boo mọlẹ.

Nigba to n sọ ero rẹ lori isẹlẹ yi, asofin agba kan , Senatọ Ben Murray-Bruce loju opo Twitter rẹ ni " yoo kuku dara ki awọn aarẹ to ti dari ilẹ yi kọja bẹrẹ sini maa ks iwe si aarẹ ilẹ wa nitori ni kete ti Oloye Ọbasanjọ kọ iwe, ni ijọba kede pe igbimọ to wa fun eto atunto orilẹede yi yoo gbe abọ rẹ kalẹ, bẹẹ naa tun ni wọn sọ Babachir Lawal sahamọ. Boya yoo tiẹ tun ya ijọba lara bayi lati kọju oro sawọn fulani darandaran to n jẹ aye familete kin tutọ."

Bakanaa, ni Gomina ipinlẹ Gombe, to wa labẹ asia ẹgbẹ oselu APC , Alhaji Hazzan Ibrahim Dankwanbo naa koro oju si bo se gba ijọba lakoko, ko to gbe akọwe ijọba tẹlẹ naa, to si n beere pe " se nitori wipe Oloye Ọbasanjọ kọwe lana si ileesẹ aarẹ, ni wọn se n tete sọ Babachir Lawal si ahamọ? Kin lo si de to fi gba ijọba ni odidiọdun kan ,ko to mu afurasi iwa ijẹkujẹ naa.

Amọ lero awọn eeyan min, ijọba gbe Babachir Lawal lati si oju awọn ọmọ ilẹ yi kuro lara lẹta ti Oloye Ọbasanjọ kọ ni, ko si tun jẹ kawọn ọmọ ilẹ yi maa ri nkan min gbejo kiri yatọ si ọrọ awọn Fulani Darandaran.

Lakotan, ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni wọn ti wa n kesi jọba ilẹ wa pe ko san sokoto rẹ, ko si le, nidi kikọ oju oro si iwa ibajẹ, ko si tun gbe Ọgbẹni Maina, ti ajọ EFCC n wa.