Amẹrika: Ipa ti idẹnukọlẹ isejọba ni lori araalu

Ọjọ manigbagbe ni ọjọ ẹti, ọjọ kọkandinlogun osu kinni ọdun yii jẹ fun orilẹede Amẹrika nitori bi ẹnu awọn asofin lorilẹede naa ko se ko lori aba ilana owona fun ilẹ naa. Aba yii ko wa fun ipese owona fun gbogbo ọdun 2018, amọ yoo se iranwọ fun ijọba ilẹ Amerika lati maa ri owo gbọ bukata rẹ titi wọ idaji osu to n bọ.

Kin lo fa sababi isẹlẹ yi?

Awọn asofin apapọ lorilẹede Amerika lo nira fun lati panupọ buwọlu aba inawo naa, ti wọn si fi ibo didi yanju ọrọ naa, eyi to mu ki ọrọ pakasọ, ti awọn asofin to tako aba yi si pọ ju awọn to faramọ lọ, eyi to mu ki eto ijọba ilẹ Amerika gba isinmi fun igba diẹ lati sjs ẹti to kọja.

Ibo aadọta si mọkandinlaadọta ni wọn di lọjọ ẹti nile asofin naa, eyi to mu ko nira lati kede ẹni to bori pato.

Awọn asofin ẹgbẹ oselu Democrat lo faake kọri lati faramọ aba ẹnawo naa, titi ti wọn yoo fi wa nkan se lori atunse ofin eto irinna silẹ Amẹrika, ti aabo yoo si wa fawọn ajoji atohunrinwa ọmọ ilẹ okeere toto ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹjọ ti wọn ko ni iwe igbelu nilẹ Amẹrika amọ ti wọn wọ orilẹede naa gẹgẹbii ọmọde, bẹẹ si ni gbogbo aayan lati jẹ kawọn asofin naa faramọ aba eto isuna yi lọjọ isinmi ana lo fori sanpọn., ti wọn si sun eto idibo lati fopin si eto isejọba to dẹnukọlẹ ranpẹ to n waye nilẹ Amẹrika siwaju di aago marun irọlẹ oni ọjọ aje.

Kin lo fa ikunsinu laarin awọn asofin yi?

Labẹ eto iselu alagbada, aba ẹnawo naa nilo awọn asofin bii ọgọta lati fontẹ luu, ninu ọgọrun asofin to wa nile asofin agba ilẹ Amẹrika. Amọ lọwọ-lọwọ bayi, asofin agba mọkanlelaadọta lo jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu Republic ti aarẹ Donald Trump ti wa, nitorinaa, wọn nilo atilẹyin awọn asofin latinu ẹgbẹ oselu Democrat, ki wọn to lee ri ọgọta asofin ti yoo buwọlu aba naa.

Amọ nigba to jẹ pe, bu fun mi, kin bu fun ọ, ni ọpọlọ nke lalẹ odo, eyi naa lo mu ki awọn asofin latinu ẹgbẹ oselu Democrat se n beere pe ki aarẹ Trump naa bawọn dunadura pẹlu aba to nii se pẹlu ofin eto irinna silẹ Amẹrika gẹgẹbi ara ofin to wa ninu aba eto ẹnawo naa, amọ tawọn ọmọ ẹgbẹ oselu Republican kọ jalẹ lati tẹwọgba ibeere wọn naa, eyi to mu ki ohun gbogbo dojude.

Awọn asofin ẹgbẹ Republican ntiwọn nfẹ ki ijọba pese owona lati fi gbọ bukata lori eto aabo lawọn lẹnu bode ilẹ Amẹrika, to fi mọ igbesẹ mimọ odi lẹnu bode ilẹ Mẹxico ati atunse ofin irinna to fi mọ afikun owona fun ileesẹ ologun.

Awọn ẹgbẹ oselu mejeeji si lo ti n fi ọwọ gun ara wọn nimu lori ẹni to jẹbi isẹlẹ yi biotilẹjẹpe ko sẹni to lee sọ pato ẹni to ni ẹbi isẹlẹ yi.

Kinni aba to n fa awuyewuye yi da le lori?

Aba yi, to nii se pẹlu eto inawo nilẹ Amẹrika, lawọn asofin ilẹ naa gbọdọ buwọlu, ko to di pe aarẹ Donald Trump fọwọsi, eyi si gbọdọ waye ko to di aago mejila oru ọjọ ẹti to kọja, amọ igbesẹ yi ni ko seese, ti ọrọ naa si di kọ, tawọn asofin ko si lee fẹnu ko lori ilana ti aba eto ẹnawo naa yoo gba, eyi to sokunfa bijọba ilẹ Amẹrika se gbe ilẹkun rẹ ti fun igba diẹ na.

Ipa wo ni isẹlẹ yi yoo ni lori awọn olugbe ilẹ Amerika?

•Ọpọ awọn osisẹ lorilẹede naa ni ko ni lee lọ sẹnu isẹ nitori ko si owo ti wọn yoo gba, ti wọn si gba ile wsn joko, sugbọn awọn osisẹ kan ti isẹ wọn nii se pẹlu ẹmi ọmọniyan, to tun jẹ kosemase nikan ni wọn yoo maa se lọ sẹnu isẹ titi ti awọn asofin agba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu Democrat ati Republican yoo fi fi ẹnu ọrọ jona , ti wọn yoo si dijọ fọwọsi aba naa.

•Segesege ni eto irinna ofurufu yoo maa se biotilẹjẹpe o wa labẹ isẹ koseemase.

•Bakanaa, o seese ko nira diẹ lati gbe iwe irinna jade, o si to ẹgbẹrun lọna igba awọn eeyan to n beere fun iwe asẹ irinna, ti wọn ko tii gbe iwe wọn jade, ti wọn yoo si gbe ẹnu ọna awọn ileesẹ yi ti lasiko ti idakureku fi ba eto isejọba yi.

•Gbogbo ilẹkun awọn ibudo igbafẹ bii ibudo isenkan isẹnbaye lọjọ si, to fi mọ ibudo itọju ẹranko lorilẹede Amẹrika, ni yoo wa ni titipa.

•Ileesẹ to wa fun eto ipawowọle labẹle ni yoo maa gba owo wọle amọ wọn yoo gbẹkẹle eto ayẹwo iwe owo sisan.

•Biotilẹjẹpe awọn osisẹ eleto idajọ ko ni pa isẹ wọn ti loju ẹsẹ, amọ inu owo to wa nipamọ ni wọn yoo fi maa san owo awọn adajọ atawọn osisẹ lẹka eto idajọ titi di ọjọ kẹẹdogun osu kẹwa ọdun, eyuu ti ọrọ yi ko ba tii lojutu.

•Ida marunlelaadọta ninu ọgọrun awọn osisẹ eleto ilera ni yoo gba ile wọn joko lẹka eto ilera, tawọn to ba wa lẹnu isẹ, yoo maa sisẹ diẹdiẹ, bẹẹ ni wọn ko ni gba alaisan tuntun wọlesileiwosan.