Christmas messages: Buhari, Biden, Akufo-Ado, Macron àtàwọn adarí míì fi ìkíni ọdún ránṣẹ́

Merry Christmas wishes images

Oríṣun àwòrán, President Joe Biden

Awọn kristẹni kaakiri agbaye ti n ṣe ọdun Keresimesi, lati sami ọjọ ibi Jesu Kristi.

Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdọdun si ni wọn ya sọtọ lati maa ṣe ọdun naa.

Ninu ọrọ ikini lati sami si ayẹyẹ ọdun ọhun, ọpọ awọn adari lo ti sọ pe ajakalẹ arun Coronavirus to mi gbogbo abaye titi lo jẹ ki ohun gbogbo le koko ni Keresimesi ọdun yii amọ wọn ni ki awọn alatilẹyin wọn fi ọkan balẹ, nitori ohun to n tan ni ọdun eegun ni ọrọ arun naa yo pada ja si.

Ẹwẹ, awọn adari orilẹ-ede kan ti fi ọrọ ikini ranṣẹ si awọn eeyan wọn kaakiri agbaye.

Aarẹ Muhammadu Buhari

Nigeria president Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Buhari ni oun darapọ mọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati sami si ayẹyẹ ọdun naa.

O ni bi ayajọ ọdun naa ṣe n mu irẹpọ wa laarin awọn eeyan kaakiri agbaye, o n tumọ si pe ireti wa pe arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra yoo di ohun igbagbe laipẹ.

Bakan naa Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Godluck Ebele Jonathan ti ki awọn awọn araalu ku ọdun Keresimesi.

South Afrika

Merry Christmas messages

Oríṣun àwòrán, David Mabuza

Igbakeji Aarẹ South Afrika, David Mabuza ti fi ọrọ ikini ọdun Keresime si ranṣẹ si awọn araalu rẹ.

O ni asiko ọdun Keresimesi jẹ akoko lati ifẹ han si ọmọlakeji ẹni, ati lati ṣe itọrẹ aanu.

France

Merry Christmas messages: Buhari, Akufo-Ado, world leaders send goodwill message

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Macron

Awọn ọmọ ogun ilẹ naa ni Aarẹ Emmanuel Macron da oju adura ọdun Keresime kọ.

O ni "Ọkan emi atawọn araalu wa lọdọ ẹyin ọmọ ogun ori ilẹ ati oju omi ti ẹ n ṣiṣẹ takuntakun lati dabo bo wa."

Lẹyin naa lo ki awọn eeyan naa ku ọdun.

Ilẹ Gẹẹsi

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson fi akoko ọdun Keresimesi ba awọn eeyan ilẹ naa sọrọ.

O si fi akoko ọhun bẹ wọn pe ki wọn lọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lati dabo bo ara wọn atawọn ẹbi wọn lọwọ arun ọhun.

O ni "Anfani nla ni yoo jẹ fun wa atawọn mọlẹbi wa ti a ba gbabẹrẹ ajẹsara Covid-19."

Ghana

Merry Christmas wishes images:

Oríṣun àwòrán, Nana Akufo Addo

Aarẹ Ghana, Nana Akufo-Addo ti fi akoko ọdun Keresimesi rọ awọn ọmọ orilẹ-ede naa lati fi ifẹ han si ẹnikeji wọn.

O ni "Ọdun to nbọ yoo jẹ ọdun kan ti a oo gbiyanju lati sọ ọrọ aje wa ji pada."

"Mo fi akoko yii rọ ẹyin araalu lati duro ti ijọba yi lakoko yii."

Joe Biden

Merry Christmas wishes images: Buhari, Akufo-Ado, world leaders send goodwill message

Oríṣun àwòrán, President Joe Biden

Ọjọ to kangun si ọjọ ọdun Keresimesi naa ni Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden sọ pe iyawo oun ti lọ ṣabẹwo si ile iwosan ti wọn ti n tọju awọn ọmọ wẹwẹ.

O ni adura oun ni ki gbogbo araalu wa ni alaafia ati idunnu lasiko ọdun naa.