Election tribunal: : Ilé ẹjọ́ sún ìdájọ́ ẹjọ́ tí Jegede pè tako ìbò tó gbé Akeredolu sípò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì síwájú

Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo sipo gomina n'ipinlẹ Ondo lọdun 2020, Eyitayo Jegede lo ṣi n rọ ile ẹjọ lati yọ gomina Oluwarotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa nipo, toripe ẹgbẹ oṣelu APC ni ko tẹle ilana to tọ lati yan wọn bi oludije labẹ asia ẹgbẹ naa.

Jegede lo sọ eleyi ninu ẹbẹ rẹ niwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun to joko lonii lati gbọ awuyewuye ẹjọ to ṣuyọ lẹyin ti igbimọ igbẹjọ idibo da Akeredolu lare ni ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yi.

Agbẹjọro fun Jegede, amofin agba Oyeachi Ikpeazu sọ pe, iwe ti ẹgbẹ oṣelu APC fi ṣọwọ si ajọ INEC leyi ti gomina Mai Mala Buni ti ipinlẹ Yobe buwọlu ni ko b'ofin mu nitori ipo rẹ.

O ni Buni ni ofin ẹgbẹ oṣelu APC tako lati buwọlu iwe ọun ati pe ofin idibo ilẹ yii tako ni abala kẹtalelọgbọn, ti iwe ofin orilẹ ede yi ti ọdun 1999 si tun baa wi ni abala 277, 182 ati 183.

O tẹnu mọ pe ọrọ yii kii ṣe ẹjọ ti wọn le pe ṣaaju idibo nikan ati pe eyi kii ṣe ayọjuran si ohun to n ṣẹlẹ l'ẹgbẹ oṣelu APC, amọ ọrọ to nii ṣe pẹlu ofin ilẹ yi ni.

Awọn agbẹjọro fun Akeredolu, igbakeji rẹ, ẹgbẹ APC ati ajọ INEC, amofin agba Akin Olujimi, Lateef ati Charles Edosanmwon ni wọn jumọ tako ọrọ agbẹjọro Jegede, ti wọn si panu pọ wipe ẹjọ to yẹ ki wọn pe ṣaaju akoko idibo ni ẹjọ ọun.

Ninu atotonu awijare awon igun ninu ipejo naa, eyi ni, Akeredolu, Ayedatiwa, egbe oselu APC ati ajo eleto idibo, ile ẹjọ wa so wipe igbimo olugbejo naa ta'sẹ agere s'ofin nitori pe ko lagbara labe ofin lati gbọ ejo naa ,ti won si menuba awon apẹẹrẹ orisirisi ẹjẹ niwaju ile ẹjọ to ga julo nilẹ wa ati ile ẹjọ kotẹmilọrun lati gbe awijare wọn lẹsẹ.

Bakan naa, ni wọn tun woye pe ẹjọ naa ni wọn pe lakoko ti ọjọ ti re kọja lati ṣe bẹẹ ati wipe ile ẹjọ ti ko yọ ni wọn tun gbe ẹjọ naa wa niwọn igba to je pe ohun to ṣẹlẹ siwaju eto idibo ni, ti won si rọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lati fagile ipẹjọ Jegede wipe ko f'ẹsẹ mule rara.

Igbimọ onidajọ ẹlẹni mẹta labẹ idari adajọ Theresa Ngolika Orji - Abadua wa sun ọjọ idajo si ọjọ iwaju lori awọn ipẹjọ kotẹmilọrun mẹrẹẹrin to wa niwaju rẹ .