Black lives Matter: Yomi Faparusi sọ ìrírí rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá nílẹ̀ Amerika

Ọmọ Naijiria to wa nilẹ Amerika ti sọrọ nipa ifiyajẹni ti wọn n koju nitori pe wọn jẹ alawọdudu.

Arakunrin, Yomi Faparusi to ba BBC Yoruba sọrọ ni pe ko si alawọdudu to wa nilẹ Amerika ti ko i tii jẹya lọwọ awọn ọlọpaa alawọfunfun.

Faparusi salaye pe wọn ma n dẹyẹ si wọn bi ẹni pe ki n ṣe Olorun lo da wọn.

O ni gbigbe ni ilẹ Amerika da bi ẹni pe awọn ko lẹtọ si awọn nkankan gẹgẹ bi eniyan, nitori awọn ko gbọdọ ko ọwọ si apo ti ọlọpaa ba n sọrọ.

Ọmọ Naijiria naa fikun pe ayipada ti de lati igba ti George Floyd ti ku.

Ti awọn eniyan si ti bẹrẹ ifẹhọnu han fun ọpọlọpọ ọjọ lati tako ifiyajẹni ati iṣekupani eniyan nitori wọn jẹ alawọdudu.

Ẹkunrẹrẹ fidio naa salaye ọna abayọ si idẹyẹsi awọn alawọdudu.