Akure Explosion: Bọ́mbù ni, bọ́mbù kọ̀ ọ́! Àlàyé rèé lẹ́nu awakọ̀ tó mọ̀ nípa ìbúgbàmù tó la ọ̀nà sí méjì l'Akurẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2020, ni ọpọlọpọ awọn olugbe ilu Akurẹ ati awọn agbegbe to sunmọ deede gbọ iro ariwo nla kan laarin oru.

Ariwo nla naa mu ki ọpọ o maa beere pe ki lo le pa iru ariwo bẹ ẹ.

Nigba ti ilẹ yoo fi mọ, ọpọ eniyan ti gba adugbo Ẹlẹyo-wo to wa ni ẹyin odi ilu Akurẹ ni oju ọna Akurẹ si Ọwọ, nibi ti ariwo nla naa ti wa.

Dide ti awọn eniyan de ibẹ ni wọn ri nkan iyalẹnu pe, oju ọna naa ti la si meji, ti ọpọlọpọ ile naa si di awo ku.

Eyi to fihan pe iṣẹlẹ nla kan ṣẹṣẹ waye nibẹ ni.

Ọpọ lo si n wadii pe ki lo le fa iru iṣẹlẹ naa.

Awọn miran ti ẹ n sọ lori ayelujara pe awọn lero pe opin aye ti de ni.

Bẹ ẹ ni awọn kan n sọ pe nkankan lo jabọ lati oju ofurufu to si fa a.

Awọn kan sọ pe ado-oloro lo bu gbamu ni agbegbe naa.

Ṣugbọn kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Ondo, sọ pe kii ṣe ado-oloro.

O sọ nigba naa pe ọkọ akẹru kan lo n ko eroja ibugbamu lati ibi kan si ekeji. To si jẹ pe ọkọ naa bajẹ loju ọna, lẹyin naa si ni awọn ibugbamu to ko gbina, to si fa iṣẹlẹ alagbara naa.

Alaye ti kọmisana ọlọpaa ṣe yii ko da awuyewuye ati ibeere to n jẹyọ lori ohun to fa iṣẹlẹ naa gan an.

Ṣugbọn ninu ifọrọwanilẹnu wo kan ti ileeṣẹ amohunmaworan ijọba ipinlẹ Ondo, OSRC, ṣe, pẹlu awakọ ọkọ akẹru naa, lo ti fojuhan pe o ṣeeṣe ko jẹ otitọ ni ọrọ ti kọmisana ọlọpaa sọ.

Awakọ naa, Isiaka Yinus, to ṣi wa ni ileewosan ijọba sọ pe owurọ ọjọ Ẹti ni ọga oun to ni ọkọ akẹru naa pe oun lati ko ẹru kan to wa ninu ọkọ akẹru miran to bajẹ si ilu Oṣu nipinlẹ Ọṣun lọ si ilu Auchi nipinlẹ Edo.

Yinusa ṣalaye pe ọkọ naa yọnu lọna, eyi si mu ki awọn (oun ati awọn oṣiṣẹ alaabo to tẹle ẹru) pinnu lati sun mọju si oju ọna.

O ni laarin oru ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ alaabo naa wa ji oun ninu ọkọ ti oun sun si pe eefin n ru jade lati abẹ ọkọ.

Ti ọlọpaa to jẹ olori ikọ alaabo naa si sọ pe ki wọn o sun kuro ni ayika ibi ti wọn wa nitori pe aarin igboro ni.

A ko ti i rin jina ti awọn ọlọpaa to wa ninu ọkọ lẹyin ọkọ akẹru mi fi sọ pe ki n duro. Nigba ti ao si fi duro, a ri i pe ina ti n jo ni abẹ ọkọ mi.

Gbogbo igbiyanju wa lati pa ina naa lo ja si ofo. Koda, awọn ọkọ miran to n lọ gbiyanju lati ran wa lọwọ.

Mo kan ṣa a gbọ ti ẹnikan lara awọn ọlọpaa na n sọ pe "gbogbo eeyan, ẹ ma a salọ."

Ibi ti mo ti n sare lọ ni mo ri i pe nkankan ba mi, nkan ti mo si mọ kẹhin naa niyẹn."

Ẹlomiran ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, to tun jẹ ọmọ ẹyin ọkọ miran to n lọ lasiko naa sọ fun ileeṣẹ OSBC pe irin nla kan lati ara ọkọ to bu gbamu ọhun lo ba oun ti oun fi deero ileewosan.

Irọ́ ní, kìí ṣe àdó olóró ló bú gbàmù ní Akure - Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá Ondo!

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti ni iro ni iroyin to n kaakiri pe ado oloro lo bu gbamu ni ipinlẹ Ondo

Akeredolu sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niibi to ti lọ ṣe abẹwo si ibi ti isẹlẹ naa ti waye.

O kesi awọn eniyan ara ipinlẹ naa lati kuro ni agbeegbe ti níbí ìbúgbàmù naa nítorí àrùn Coronavirus.

Gomina Akeredolu lasiko to ṣe abẹwo si ibi ti ibugbamu naa ti waye sọ fun awọn eniyan ki wọn ranti arun Coronavirus wa nita nitori naa ki wọn sọra lati sun mọ ara wọn.

Akeredolu parọwa si awọn eniyan lati fun awọn agbofinro ni anfaani lati ṣe iwadii ni ẹkunrẹrẹ lori ohun to sẹlẹ.

Amọ, o ni gẹgẹ bi ọrọ awọn agbofinro, ọkọ ileeṣẹ to n ṣẹ okuta, lo gbe awọn ohun elo ibugbamu ti wọn fi n sisẹ, eleyii to fa ibugbamu naa.

Ìbúgbàmù ńlá ba ìlé méjì jẹ́, la ọ̀nà sí méjì ní ìlú Akure!

O kere tan ile meji ti awọn eniyan n gbe, ileewe ati ile ijọsin lo wo ni ilu Akure lẹyin ti ibugbamu dun ni ipinlẹ Ondo.

Agbẹnusọ Ileesẹ Ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro lo fi ọrọ naa lẹde fun BBC News Yoruba

Tee-Leo Ikoro ni ileesẹ to n ṣe awọn ohun elo ti wọn fi n ṣe oju ọna lo fa ibugbamu naa, amọ kii sẹ ado oloro.

O ni ohun elo ibugbamu naa ya ọna to wa ni opopona to lọ si papakọ ofurufu ni ipinlẹ naa jẹ ati ile meji to wa ni ẹba ọna ni agbeegbe Eleyowo ni ipinlẹ naa.

Iroyin fi lede pe awọn eniyan to wa ni agbeegbe naa fi ara pa, ki o to di wi pe iranwọ de.

Agbẹnusọ Ileesẹ Ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni ko si ẹmi to sọnu ninu iṣẹlẹ naa, sugbọn awakọ naa farapa to si n gba itọju lọwọ ni ile iwosan ni ipinlẹ naa.

Amọ, Oluyemi Fasipe loju opo Twitter rẹ s wi pe ibugbamu naa ba awọn ile ati dukia jẹ, to fi mọ ile epo to wa ni agbeegbe Ogbẹsẹ.

Bakan naa ni wọn ibugbamu naa la ọna naa si meji, to fi mọ ile ijọsin ni agbeegbe naa.

Arabinri Temidayo ni oju opo Twitter rẹ sọ wi pe ibugbamu naa nkan jẹ ninu ile wọn.