Apollo 11: Àgbáyé sayẹyẹ ọdún 50 tí ènìyàn kọ́kọ́ wọ inú Osupa

Apollo 11

Oríṣun àwòrán, AFP

Ẹgbẹgbẹrun eniyan kaakiri agbaye lo n se ayajọ aadọta ọdun ti eniyan kọkọ wọ inu Osupa.

Ni Ogunjọ, Osu Keje, ọdun 1969 ni ọkọ ofurufu Apollo 11 to gbe wọn lọ si inu Osupa sọkale si ile isẹ ofurufu, Tranquility Base.

Neil Armstrong lo si koko je eni akoko to fi ese rin ni ori osupa, ti opolopo awon aworawo si ma n se odun yii kaakiri agbaye ni odoodun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Armstrong, lasiko to n rin lori ofurufu naa sọ wi pe ‘igbesẹ akọkọ niyii fun eniyan, ipa pataki fun ara aye’.

Ajọ to n si sami ayẹyẹ aadọta ọdun ti eniyan wọ inu osupa naa NASA, pẹlu sise afihan fidio bi wọn se wọ inu osupa ọhun, eyi to fun iran tuntun to le ni idaji biliọnu kan lanfaani, lati ri ohun to sẹlẹ ni aadọta ọdun sẹyin.

Neil Armstrong

Oríṣun àwòrán, NASA

Ni oju opo Twitter rẹ, Aldrin to jẹ ẹnikeji to gun inu Osupa naa sọ wi pe‘ aadọta ọdun sẹyin, orilẹede Amẹrika lo kọkọ wọ inu Osupa, ti ọgọọrọ miliọnu ọmọ ilẹ Amẹrika si duro tiwa ni gbogbo asiko naa.’

Àkọlé fídíò, Fidio yii se afihan bi Buzz Aldrin, Michael Collins ati Neil Armstrong se kọ́kọ́ wọ inu Osupa ní Ogúnjọ́, Osù Keje, Ọdún 1969.

Awọn akẹẹgbe Neil Armstrong, Buzz Aldrin ati Michael Collins ti wọn jọ de inu Osupa, ni wọn bi ni ọdun 1930.

Aldrin ati Collins si wa laye, amọ Armstrong ku ni ọdun 2012 ni ẹni ọdun mejilelọgọrin.