80 years Masters Graduate: Mo ṣi máa kàwé gboyè PhD

Haruna Igboro jẹ apẹrẹ ẹni to maa ni ọkan lile ninu ohunkohun to ba fẹ ṣe.

Ẹni ọgọrin ọdun ni baba Haruna Igboro.

O ṣalaye fun BBC pe lati kekere olun ti ni ipinu lati kawe rẹpẹtẹ lẹyin ti baba rẹ ku.

Nitori idi eyi lati nkan bi ọmọ ọdun mẹrin lo ti n tiraka lati kawe lati ile iwe alakọbẹrẹ lọdun 1951.

Titi ti baba yii fi ka a dori gbigbaa oye Masters bayii lẹni ọgọrin ọ̀dun, ohun funra rẹ ni iwuri ara rẹ nipa titọ ara ẹni.

Pẹlu gbgbo ipenija to koju, o ṣi fi aridaju ipinu rẹ han lati jẹ ki gbogbo ọmọ rẹ atawọn to ba pade rẹ nigbagbọ ninu aforiti.