Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàrin àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Ogun #BBCGOVDEBATE

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bó ṣe ń lọ níbi ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Ó dìgbà kan ná!

    Ẹ ṣeun tí ẹ dara pọ̀ mọ́ wa látàárọ̀ lórí ìtàkùn yìí. A lérò pé ẹ gbádùn gbogbo bí ó ṣe lọ láti ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àwọn olùdíje gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun lónìí. Ẹ máa kàn sí wa lórí ìtàkùn www.bbcnews/yoruba àti lójú òpó facebook wa, bbcnewsyoruba. Látẹ́nu Yetunde Olugbenga tó ń jábọ̀ àti BBC Yoruba, ó dìgbà kan ná.

  2. Ojú òpó Facebook

    Ojú òpó Facebook
    Àkọlé àwòrán, Ojú òpó Facebook
  3. Ojú òpó Facebook

    Ojú òpó Facebook
    Àkọlé àwòrán, Ojú òpó Facebook
  4. Àwọn aráalé ṣì ń dáhùn ìbéèrè láàrin ara wọn

    Lójú òpó Facebook BBC News Yoruba, awọn eniyan ṣi tẹsiwaju ninu ifọrọwerọ, ibeere ati idahun to fi mọ itahun sira ẹni.

    Ipade ifọrọwerọ BBC Yoruba
    Àkọlé àwòrán, Ipade ifọrọwerọ BBC Yoruba
  5. Orin orílẹ̀èdè Nàìjíríà ló kádìí ètò

    Atawọn akopa atawọn oludije lo dide lati kọorin orilẹèdè Nàìjíríà lati kasẹ eto ipade ifọrọwerọ naa nilẹ.

    Dide lati kọ orin orilẹede Naijiria
    Àkọlé àwòrán, Dide lati kọ orin orilẹede Naijiria
  6. Paseda ni ki wọn o ma ran ọmọde niṣe ki wọn ran paseda nise. O ni oun setan lati pa ìṣẹ́ da ati lati pa ìṣe awon Obayejẹ oloselu da

  7. Ogunbanjo ni oun lomode to wa laarin wọn. Omode si ni a n ran nisẹ. Ki awon eeyan ipinle ogun o ran oun nise. O ni oun ko lee dáa ṣe lai si iranwọ araalu. O ni ki won ma ta ibo wọn. O ni bi won ba gbe owo wa ki won gbaa nitori won n fi owo abu se abu lalejo ni.

  8. Isiaka sọ̀rọ̀ ni ede Ẹgba o si tun salaye pe oun yoo sejoba pelu ogbon, imo, oye ati ifokansin ati iberu Olorun.

  9. Ọ̀rọ̀ ìkádìí àwọn olùdìbò

    Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu ANN ni bi oun ba di gomina, gbogbo nnkan ti oun ti ko ninu oselu ni oun yoo lo lati rii pe ipinle ogun lo siwaju. O ni ijoba oun yoo lo de gbogbo esekuku ati igberiko oun ko si ni ye kuro lori ohun ti oun sọ.

  10. Fun paseda,

    Se yoo seto eyawo fawon oloja?

    Paseda ni oun ti n se eyi gan lati bii odun die seyin.

  11. Ibeere fun isiaka,

    lori pe ko tii de woodu kewa ago Owu.

    Isiaka ni ko si wọọdu kanan ti oun ko tii de ni ipinle Ogun.

  12. Asiko ibeere
    Àkọlé àwòrán, Asiko ibeere
  13. Fun Akinlade,

    Kini eto ikera fawon alaisan foni ku fọla dide?

    Akinlade ni idanilẹkọ yoo wa faraalu lori rẹ.

  14. Fun Paseda,

    Ki lo de to fi UPN lo si SDP?

    Paseda ni oun ri APC, PDP nilẹ lai ya sibe. O ni egbe ti oun farajo naa ni ẹgbẹ MKO Abiola tii ṣe SDP ti oun si darapo mọ ọ

  15. Fun ogunbanjo,

    Ibeere ni pe bawo lo se lee seto lilo ẹgbin ati idoti fun ipese ina oba?

    Ogunbanjo ni awon yoo lo awon egbin lati pese ina oba

  16. Fun Isiaka,

    Ki ni won ni fawon to kose ti ko lowo irin ise tabi awọn to kawe ti ko tii riṣẹ?

    Isiaka ni anfani yoo wa fawon onisowo kereje. O ni eto ekose ọwọ yoo wa fawon akekojade pelu

  17. Èèyà kan ń fẹ́ kí Akinlade sọ oun tó ṣe fún agbègbè Ipokia.

    Lara awọn akopa bere ibeere taara lọwọ Akinlade.

    Akinlade ni oun ti se eto lawon ileewe ni agosasa, ijofin, ajere, ilaro ati beebee lo

    Akinlade
    Àkọlé àwòrán, Akinlade
  18. Paseda ni ọpọ ijọba ni kii ranti akanda. Bi oun ba de ipo oun yoo yan komisana laaarin wọn.

  19. 'Mo máa yan kọmísánà àkàndá ẹ̀dá' - Ogunbanjọ, Ogunbanjọ: Àmọye èèyàn ló wà níjọba tí orí wọn kò pé

    Ogunbanjo ni oun tako yiyan akanda eda sipo bayii bii ka ni olugbaninimọran. O ni oun yoo yan akanda eda gege bii komisona gidi ni.

    Ogunbanjo
    Àkọlé àwòrán, Ogunbanjo
  20. Paseda ni eto adojutofo ẹmi gbodo wa fun awọn ti ko lagbara rẹ ni kii se lati kan ko owo fun awon eeyan kan.