You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ìròyìn ìbúrawọlé jákèjádò orílẹ̀èdè Nàìjíríà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Aarẹ Muhammadu Buhari, igbakeji rẹ, awọn gomina ipinlẹ ati awọn igbakeji wọn ni wọn bura fun lonii

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga and Busayo Akogun

  1. Ó dìgbà kan ná!

    Ẹ̀ ṣeun ti ẹ dara pọ̀ mọ́ wa lónìí fún ìròyìn káàkiri Nàìjíríà níbi tí ètò ìbúrawọlé ti ń wáyé.

    Ẹ máa kàn sí bbc.co/yoruba ní gbogbo ìgbà fún àwn ìròyìn àtìgbà dé ìgbà.

    Látọwọ́ Yetunde Olugbenga àti Busayo Akogun tó ń jábọ̀, a dúpẹ́ púpọ́ lọ́wọ́ yín.

    Ó dìgbà kan ná!

  2. Wo àwọn ààrẹ Nàìjíríà láti 1999 títí d'òní

  3. Sowore: Ìjọba pàṣán ni ìjọba Buhari

    Oludije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC ninu idibo to kọja ni "bi ẹ ba wo o dadaa, inu awn ọmọ Naijiria ko dun si eto to n lọ lonii".

    Lori pe aarẹ́ Buhari ko sọ̀rọ̀ iburawọle si awọn ọm Naijiria, Omoyele Sowore ni ijọba paṣan ni Naijiria wa yii eyi ti o ta ba ara ile ta ba ara oko".

    O ni aarẹ ko sọrọ tori pe ki lo fẹ sọ to jẹ́ wi pe irọ ni gbogbo rẹ.

  4. Ifeanyi Ugwuanyi ti Enugu rèé ní gbàgede ìbúrawọlé

  5. Gomina Dave Umahi ti ìpínlẹ̀ Ebonyi búrawọlé

  6. El Rufai búrawọlé fún sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Kaduna

  7. Gómìnà Badaru Abubakar ti ipinlẹ̀ Jigawa bùrawọlé

  8. Dapo Abiodun gbàjọba lọ́wọ́ Amosun

  9. Òjò ń pa Sanwoolu!

    Gẹ́lẹ́ ti Gomina tuntun ti ipinlẹ Eko Babajide Sanwoolu gun ori pepele lati burawọle niwaju adajo lojo bẹrẹ si ni bọ́ to bẹẹ̀ ti wọn sare ga agboojo le gomina tuntun lori.

  10. Awọn àlejò jànkàn-jànkàn l'Abuja

    Lara awọn eekan oṣelu Naijiria ree gẹgẹ bi alejo pataki nilu Abuja nibi eto ibura wọle.

  11. Babajide Sanwoolu búrawọlé Eko

  12. Igbakeji gomina tuntun nipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan ti bura wọle.

  13. Aarẹ Buhari ko ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lẹyin ibura

    Ni kete ti Aarẹ Muhammadu Buhari burawọle fun saa keji - Aarẹ kan ka ọrọ ibura rẹ ni. Lẹyin naa lo tẹwọ gba asia tuntun lati ṣilẹkun fun saa rẹ keji, to si rin kiri ninu ọkọ ni eto iburawọle naa wa si opin.

    Aarẹ ko wulẹ sọrọ apilẹkọ kankan gẹgẹ bii ti atẹyinwa fun gbogbo aarẹ tabi gomina tuntun ti wọn ba bura fun.

    Aṣe jijuwọ pe o dabọ, o ya nile ni aarẹ ju si awọn ọmọ Naijiria.

  14. Àwọn ará Kwara ni "Idẹra dé"

    Lara awọn esi ẹyin ololufẹ wa rèé lójú opo Facebook bbcnewsyoruba

  15. Abdulrazak Abdulrahman ti Kwara jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú adájọ́

  16. Èrò wọ́ tẹ̀lé Seyi Makinde lọ ibi ìbúrawọlé l'Oyo

    Kẹti kẹti ni ero wọ tẹle amoju ẹrọ Seyi Makinde ati iyawo rẹ lọ si ibi eto iburawọle ni ipinlẹ Oyo

  17. Ètò ìbúrawọlé ní ìpínlẹ̀ Eko

    Igbakeji gomina ipinlẹ̀ Eko, Obafemi Hamzat, iyawo ati awọn ọmọ rẹ lori pepele iburawọle.

  18. "Mo ṣèlérí láti fọkàn sin orílẹ̀èdè Nàìjíríà"

    Ààrẹ Buhari rèé tó ń búra níwájú adájọ́ àti gbogbo ọmọ Nàìjíríà

  19. Alaafin ilu Ọyọ de sibi iburawọle gomina Ọyọ

  20. Gbàgede TBS l'Eko ń rọ́ kẹ̀kẹ̀ ní ìgbáradì de ìbúrawọlé

    Gbagede Tafawa Balewa Square ni eto iburawọle ti ipinlẹ Eko yoo ti waye.

    Lọwọ lọwọ, awọn eniyan ti wa nikalẹ ti awọn onilu si n fi ilu ki awọn eeyan kuabọ bi wọn ṣe n wọle si gbagede.

    Bakan naa ni olori ikọ ogun amuṣẹya ro dẹdẹ ni imura ologun ki aabo lee daju nibi eto iburawọle.