Eyi ni opin iroyin yajo-yajo lori bi eto idibo se n lọ ni ipinlẹ Ekiti.
Sugbọn a tubọ tẹsiwaju lati maa bun yin gbọ nipa awọn iroyin eto idibo ni ipinlẹ Ekiti lori oju opo iroyin wa tii se www.bbc.com/yoruba.
Ẹ seun pupọ, tẹ dara pọ mọ wa.
A ń mú ètò gbogbo bó ṣe ń lọ níbi ìdìbò fún ipò gómínà káàkiri ipinlẹ Ekiti.
Olubusola Afolayan and Adedayo Owolabi
Eyi ni opin iroyin yajo-yajo lori bi eto idibo se n lọ ni ipinlẹ Ekiti.
Sugbọn a tubọ tẹsiwaju lati maa bun yin gbọ nipa awọn iroyin eto idibo ni ipinlẹ Ekiti lori oju opo iroyin wa tii se www.bbc.com/yoruba.
Ẹ seun pupọ, tẹ dara pọ mọ wa.
Awọn oludibo n fo fayọ nigbati wọn ka esi ibo, ti APC si wọle.
Ẹgbẹ oselu PDP lo ti n kọkọ fo soke tẹlẹ, amọ nigba ti wọn ka ibo naa, ni APC moke, ti awọn eeyan si n jijo ọpẹ.
APC - 129
PDP - 103
Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ti sọ fun awọn asoju ẹgbẹ oselu PDP to wa ni awọn agọ idibo lati mase pada wale, ti won ba ji apoti idibo wọn lọ.
Fayose sọ eyi nigba to n pe ọkan lara awọn asoju ẹgbẹ naa to wa ni Emure Ekiti.
Fayose ni oun ko fe gbọ awijare, ati wi pe ẹnikẹni ti wọn ba ji apoti idibo rẹ gbe gbọdo waa ri, abi ki o mase pada wa si Ado-Ekiti to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ekiti.
O pari ọrọ rẹ pẹlu owe wipe ‘ole o gbọdọ wa si ile rẹ, ki o gbe ẹru rẹ lọ’.‘

PDP - 452
APC - 105
PPA - 1
PANDEL - 1

AD 1
ADP 2
APC 106
PANDEL 1
PDC 1
PDP 304
PPA 2

Zury-Olanrewaju Hamzat:O ma se o! Osi, ipọnju ati aimokan-mokan ni ona ti o ga ju leleyi o. Pelu gbogbo ilani loye lori ewu ti o wa nibi ki a ma gba owo ki a to dibo. Ekun gbọn mi fun orilede yio.
Ibigbami mutairu AlabiSe eni ti won kolu ni egungun re tun ti le bayii, baba feran drama pipo ju, opolo oselu
Olaleke Olawole: Igba Iṣoro la ma n mọ Olorun, Fayose ti ni Problem, kini idi ti o fi je pe afi dandan Eleka, Fayose want cover up! wa a pe lewon Oleeee.
Aṣọ funfun ni àwọ̀n olùdíje méjì gbòógi nínú ètò ìdìbò gómìnà Ekiti, Olusọla Ẹlẹka PDP ati Kayọde Fayẹmi APC wọ loni ọjọ idibo?

Esi idibo to n tẹ wa lọ́wọ́ fi han pe APC ti jawe olubori ni ibudo idibo ti Fayẹmi.
APC 186
APA 1
PDP 2

Esi idibo ibudo ti Omoba Adeyeye ti dibo Ekiti.
APA-1
PDC-1
PDP-15
APC-176
Void-4
Awọn oludibo n fẹsun kan ọkunrin to wọ asọ búlù yii pe o mu ibọn wa si ibudo idibo ni eyi ti awọn oludibo pe ọlọpaa.
Nigba ti awọn ọlọpaa n bii leere pe kin lo wa lara rẹ, ko fesi kankan rara. Nise lo fo ọna si odikeji titi, to si wọ inu ọkọ jiibu SUV Lexus dudu kan to wa nilẹ, to si lọ.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn ọmọ ogun ilẹ̀ ti ya wọ Ado Ekiti to jẹ olu ilu ipinlẹ Ekiti bayii.
Ni wọọdu karun-un ati ikẹfa, ladugbo Okehinmi, awọn ololufẹ ẹgbẹ oselu APC ati PDP n tahun si ara wọ̀n.
Awon oludibo to ba BBC sọrọ ni Okehinmi, ward 6, unit 5 sọ pe idibo naa ni konu-n-kọhọ ninu lagbegbe naa nitori wọn n gba owo lọwọ awọn oludije.
Awọn ibudo idibo kọọkan ti pari eto idibo, ṣugbọn awọn miran ṣi n dìbò bayii.
Ajọ INEC ti kede agogo meji lati fopin si idibo Ekiti lonii.

Fayose ti so pe awon agbofinro ti ja eto idibo gbà mo ajo INEC lọwọ ṣugbọn bi o ti wu ko ri Eleka ni yoo wole.
O ni oun ni idaniloju pe oun lo ni ida ogorin ninu ọgọrun ìbò ipinle Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina Fayoṣe ti dibo ni Afao Ekiti. Ayo Fayoṣe wọ gbégun-ọrùn-ró si ọrun rẹ.

A gbọ pe loju awọn osisẹ alaabo ni awọn janduku naa ti ji apoti ibo naa gbe. Sugbọn ni kete ti awọn ọlọpaa kogbregbe (SARS) debẹ, ni wọn fi panpẹ ofin gbe awọn janduku naa.
Ni Ado Ekiti, awọn ọlọpaa naa mu oludibo meji.
Awon ọlọpaa yọ aworan iṣẹlẹ yii ti akọroyin BBC ya.
Segun Oni ni Ẹnikẹni to ba fi kaadi rẹ silẹ lati gba owo ko ni lẹnu ọrọ lati koju isejọba ipinlẹ naa.
Sẹgun Oni sọrọ naa nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to dibo ni wọọdu rẹ.
O fikun pe eto idibo naa n lọ deede, sugbon ẹrọ kaadi wọn n wọ́lẹ̀ to fa ki ẹro pọ lori ila.
Diẹ lára ọ̀rọ̀ àwọn ololufẹ BBC ni Facebook niyii:
Adesanya Folashade Asake: Ibo Ekiti wahala ti poju kinlode gannnn
Funsho Bernice: Ko poju ni temi....ti o ba fe losi ile awon ole onijibiti lati gba nkan, o nilati munra bi eni to n losi oju ogun ni.
Olaogun Olusola Isaac: Itanje lasan ni ara ipolongo egbe oselu ni; o se je pe egbe oselu PDP nikan ni gbogbo camera ati oniroyin agbaye n wa kiri. Se PDP nikan lo wa ni Ekiti ni gbogbo wa n irukan niwọn, e sinmi PDP lotun PDP losi; eyin oniroyin ko ki n se egbe kan soso lowa nibe ni oju titemi o e ti ro pe ti e ko ba wole fun ipo yi ohun ti e maa fise evidence pe ejo niyen o ma se o