Gẹ́gẹ́ bíi ìse rẹ̀ ní
ọdọọdún, ẹgbẹ́ àkọ̀ròyìn nílẹ̀ wa, (NUJ), ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà sètò àkànse
ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan láti sàmì ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n tí a dìbò June 12.
Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ alásẹ
ẹgbẹ́ NUJ àti Àgbàakin Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Olóyè lékan Àlàbí pẹ̀lú akọ̀wé
tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ MKO Abiọla ló se agbátẹrù ètò náà.
Gbọ̀ngàn Dapọ Aderọgba,
tó wà nínú ọgbà àwọn akọ̀ròyìn náà ládùgbò Ìyágankú ní ìlú Ìbàdàn ni ètò náà ti
ń wáyé.
Àkòrí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ni " Ètò ìjọ̀ba tiwantiwa ní
àná, lónìí àti ní ọ̀la."
Olóyè Asiwaju Bọla
Hammed Tinubu ni wọ́n ń retí bíi alága níbi ètò náà nígbàtí Ọ̀gbẹ́ni Akin
Onigbinde, tíí se olórí tẹ́lẹ̀ fún ilé asòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, yóò jẹ́
olùdánilẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀.