Sáà kéji tọ́ sí Buhari - Asíwájú Bola Tinubu

A ń mú ìsẹ̀lẹ̀ bó se ńlọ lọ́wọ́lọ́wọ́ níbi ìdálọ́lá Olóògbé MKO Abiola ní Abuja àti ètò ìràntí ìgbà àyé rẹ́ tó ń wáyé káàkiri ẹkùn Gúúsù-Iwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Níhìín ni a ó fi àdàgbá gbogbo àtẹ̀jáde t'òní rọ̀ sí fún bo ti ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ (BBC Yoruba Live Page) látòwúrọ̀.

    A lérò pé ẹ́ gbádùn gbogbo ìròyìn wa fún àyájọ June 12 lónìí.

    Ẹ má se kúrò rára lórí ìtàkùn wa bbc.com/yoruba

    Ó dìgbà kan ná. Ẹ seé púpọ̀.

  2. June 12 di Ọdún ìjọba Tiwa n tiwa, ó dára fún wa

    Ọjọ́ mánigbàgbé ni ọjọ́ kejìlá osù kẹfa, ọdún 1993 jẹ́ fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀.

    Àkọlé fídíò, Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ June 12 fún ìrántí yín
  3. Ìpínlẹ̀ Ekiti kò se ayẹyẹ June 12

    Ìròyìn tó tẹ̀ wá létí láti ìpínlẹ̀ Ekiti ni wípe páro páro ni gbogbo ojú pópó àti àwọn ìgboro dá.

    Ní se ni àwọn àrá ìpínlẹ̀ Ekiti mú ìsinmi tí wọ́n kéde fún ọjọ́ òní lọ́kúnkúndùn tí wọ́n sì lò ó gẹ́gẹ́ bí ànfàní àti sinmi síle wọn.

    Gómìnà Fayose kéde ìsínmi June 12 sùgbọ́n àwọ́n ará Ekiti kò se ayẹyẹ kankan

    Oríṣun àwòrán, @ekitistategov

    Àkọlé àwòrán, Gómìnà Fayose kéde ìsínmi June 12 sùgbọ́n àwọ́n ará Ekiti kò se ayẹyẹ kankan
  4. Ibadan náà kò gbẹ́yìn nínú yíyẹ́ MKO Abiola sí

    Gẹ́gẹ́ bíi ìse rẹ̀ ní ọdọọdún, ẹgbẹ́ àkọ̀ròyìn nílẹ̀ wa, (NUJ), ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà sètò àkànse ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan láti sàmì ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n tí a dìbò June 12.

    Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ alásẹ ẹgbẹ́ NUJ àti Àgbàakin Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Olóyè lékan Àlàbí pẹ̀lú akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ MKO Abiọla ló se agbátẹrù ètò náà.

    Gbọ̀ngàn Dapọ Aderọgba, tó wà nínú ọgbà àwọn akọ̀ròyìn náà ládùgbò Ìyágankú ní ìlú Ìbàdàn ni ètò náà ti ń wáyé.

    Àkòrí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ni " Ètò ìjọ̀ba tiwantiwa ní àná, lónìí àti ní ọ̀la."

    Olóyè Asiwaju Bọla Hammed Tinubu ni wọ́n ń retí bíi alága níbi ètò náà nígbàtí Ọ̀gbẹ́ni Akin Onigbinde, tíí se olórí tẹ́lẹ̀ fún ilé asòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, yóò jẹ́ olùdánilẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀.

    Ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn (NUJ) Ibadan
    Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn (NUJ) Ibadan
    Ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn (NUJ) Ibadan
    Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn (NUJ) Ibadan
  5. Àwọn tí wọ́n fi oyé dá lọ́lá

    Ní sísẹ̀ n tẹ̀lé, Ààrẹ Muhammadu Buhari fi oyè dá àwọn wọ̀nyìí lọ́lá - Olóògbe Olóyè MKO Abiola (GCFR), Olóyè Gani Fawẹhinmi (GCON) àti Olóyè Baba Gana-Kingibe (GCON)

    Buhari àti Ganiat Fawehinmi

    Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

    Àkọlé àwòrán, Buhari ń gbé àmì oyè ìdálọ́lá fún Ganiat Fawehinmi
    Kola Abiola àti Ààrẹ Buhari

    Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

    Àkọlé àwòrán, Kola Abiola gba àmì oyè ìdálọ́lá lórúkọ Bàbá rẹ̀
    Ààrẹ Buhari fún Baba Gana-Kingibe ní àmì oyè ìdálọ́lá

    Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

  6. 'IBB dalẹ̀ Abiola lẹ́yìn tó búra pẹ̀lú Koran'

    Èsì ìwádìí àwọn Dókítà nípa ikú tó pá a fihàn pé kìí se àmúwá Ọlọ́run. Ọjọ́ keje osù keje ọdún 1998 ni Moshood Kashimawo Abiola jáde láyé.

    Àkọlé fídíò, June 12: Kí ló wà nínú Tea tí Abiola mu?
  7. Àwòrán síi láti ilé MKO Abiola nílùú Eko

    Wìtì wìtì lèrò pọ̀ níle ní ilé olóògbé MKO Abiola. fún ayẹyẹìrántí ọjọ́ June 12.

    Gbọ̀ngàn kan ní ilé olóògbé Abiola
    Àkọlé àwòrán, Gbọ̀ngàn kan ní ilé olóògbé Abiola
    Àwọn akópa níbi ètò tò wáyé ní ilé olóògbé Abiola
    Àkọlé àwòrán, Àwọn akópa níbi ètò tò wáyé ní ilé olóògbé Abiola
    Inú gbọ̀ngàn ilé olóògbé Abiola
    Àkọlé àwòrán, Inú gbọ̀ngàn ilé olóògbé Abiola
    Àwọn àlejò ní ìta ilé olóògbé Abiola
    Àkọlé àwòrán, Àwọn àlejò ní ìta ilé olóògbé Abiola
  8. #DemocracyDay ń gbalẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà nítorí MKO Abiola

    Àyájọ́ #DemocracyDay ń gbalẹ̀ káàkiri orílẹ̀èdè Nàìjíríà nítorí ayẹyẹ oyè ìdálọ́lá fún olóògbé MKO Abiola lónìí ọjọ́ kejìla osù kẹfà.

    #DemocracyDay
    Àkọlé àwòrán, #DemocracyDay
  9. Ìpínlẹ̀ Eko sí ère MKO Abiola

    ìpínlẹ̀ Èkó sọkutu wọ̀wọ̀ ní àyájọ́ ‘June 12’ fún tọdún yìí, nígbàtí Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó sí ère kan tí wọn fi ń se ìrántí olóògbé MKO Abiọla ní àyájọ́ ìdìbò June 12. Yorùbá ní, báa kú làá dère, èèyàn kò sunwọ̀n ní ààyè, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ olóògbé MKO Abiọla rí, tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó sì ń bèèrè pé kí wọn fi fọ́nrán àwòrán àti ohùn ìgbà ìkẹyìn olóògbé Abiọla síta.

    Àkọlé fídíò, Ijoba Eko: Akọ́ni mánigbàgbé ni Abiola
  10. Àwọn ará ìlú Abiola ní Abẹokuta bá BBC sọ̀rọ̀

    Àkọlé fídíò, Abiola jẹ́ ẹni tí wọ́n fẹ́ràn káàkiri gbogbo Nàìjíríà

    Àwọn olùkòpá nínú ìdìbò June 12, ọdún 1993 tí wọn tún jẹ́ ọmọ ìlú Abẹokuta sọ ọ́ di mímọ̀ pé ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ìdìbò lọ déédé láàrin ẹ̀yà Hausa, Igbo àti Yorùbá.

  11. Aare Buhari fun ebi MKO ni iwe eri

    Aare Buhari fun ebi MKO ni iwe eri.

    Iwe Eri oye GCFR fun MKO Abiola

    Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

    Àkọlé àwòrán, Iwe Eri oye GCFR fun MKO Abiola
  12. Sáà kéji tọ́ sí Buhari - Asíwájú Bola Tinubu

    Olóyé ẹgbẹ́ òsèlú APC, Asíwájú Bola Ahmed Tinubu sọ pe sáà kejì lórí ipò Ààrẹ́ tọ́ sí Muhammadu Buhari gẹ́gẹ́ bí ó se fi oyè dá olóògbé MKO Abiola lọ́lá.

    Ó ní "bí gbogbo àwọn oníròyìn tilẹ̀ ń sọ pé nítorí òsèlú ni Buhari se ń se èyí, ó irú òsòlè eléyìí dára".,Ó ní òun yóò dìbò fún Ààrẹ Buhari nígbà kejì.

    Tinubu gbóríyìn fún ìgbésẹ̀ Buhari

    Oríṣun àwòrán, @ThedailyNG

    Àkọlé àwòrán, Tinubu gbóríyìn fún ìgbésẹ̀ Buhari
  13. Kò yẹ́ kó dá Abiola lọ́lá kó tún kan sárá sí Abacha - Soyinka

    Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka tó jẹ gbajúgbajà ònkọ̀wé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà tẹ pẹlẹ mọ́ ọ pé Kò tọ́ bí Ààrẹ Buhari se fi oyè dá olóògbé Moshood Abiola lọ́lá kó tún máa kọrin ìyìn Ọ̀gágun Sanni Abacha tó sọ̀nà ikú Abiola.

    Wole Soyinka pe Buhari ní ẹlẹnu méjì

    Oríṣun àwòrán, @NASO_E_BI

    Àkọlé àwòrán, Wole Soyinka pe Buhari ní ẹlẹnu méjì
  14. A dárí jì yín, a ti gba ẹ̀bẹ̀ yín - Kola Abiola

    Kola Abiola tó jẹ́ àkọ́bí ọmọkùnrin àkọ́kọ́ tí olóògbe Abiola bi dá èsì pada fún ìjọba Nàìjíríà pé ìdílé Abiola ti dárí ji ìjọba àpapọ̀.

    Sáájú, ọmọ rẹ̀ obìnrin, Hafsat ẹni tí wọ́n pa ìyà rẹ̀ nígbà wàhálà June 12 sọ pé àwọn kò mọ̀ pé ọlọ́rún lè lo Ààrẹ Buhari fún ìdíle wọn.

    Kola Abiola fèsì sí ọ̀rọ̀ Ààrẹ Buhari
    Àkọlé àwòrán, Kola Abiola fèsì sí ọ̀rọ̀ Ààrẹ Buhari
  15. Ààrẹ Buhari tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹbí MKO Abiola

    Àarẹ orílẹ̀èdè Nàìjírìà, Muhammadu Buhari lórúkọ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹbí olóògbé MKO Abiola àtàwọn míì tó fara rọ́ nínú ìsẹ̀lẹ̀ June 12,1993. Ó fi kún un pe akínkanjú ọkùnrin ogun ni àwọn tó fi ẹ̀mi wọn lélẹ̀ láti dóòlà orílẹ̀èdè yìí bíi ti MKO Abiola.

    Àarẹ Buhari sọ pé akínkanjú ni Abiola jẹ́
    Àkọlé àwòrán, Àarẹ Buhari sọ pé akínkanjú ni Abiola jẹ́
  16. Kókó, MKO Abiola ti gba oyè ìdálọ́lá GCFR

  17. Kókó, Baba Gana-Kingibe náà gba ìdálọ́lá

    Baba Gana-Kingibe ti gba oyè ìdálọ́lá rẹ̀ báyìí

  18. Kókó, Gani Fawẹhinmi gba ìdálọ́lá

    Ganiat Fawẹhinmi gba oyè ìdálọ́lá lórúkọ ọkọ rẹ̀, olóògbé Gani Fawẹhinmi.

  19. Ẹ lè wo Facebook Live wa tó ń wáyé nílé olóògbé Abiola níhin

    Àwọn àsojúkọ̀ròyìn wa ń mú Facebook Live wa sí ojú ìwòranyín lọ́wọ́lọ́wọ́ láti ilé olóògbé MKO Abiola nílu Eko.

  20. Àwon èèyàn jànkàn-jànkàn dé síbi ètò ìdálọ́lá náà

    Nisinsinyi, ọpọlọpọ awọn eniyan ati awọn oloselu ti won kopa ninu ilọsiwaju fun ifarahan ti June 12 gegebi bi ayajọ-ọjọ ijọba awa arawa ni ijoba ti fiwe pe si ibi ayeye yi, eyi ti o n waye ni olu ilu orileede Naijiria nilu Abuja.

    Awon eniyan bii Asiwaju Bola Tinubu, Oloye Bisi Akande, awọn gomina lati ipinle Kogi, Kano, Kebbi, Kwara, Benue, Nasarawa, Jigawa ati awọn Minisita repete ti wa ni ijoko bayi.

    Awon amugbalegbe fun aare Buhari naa ti wa ni ijoko pelu.