Eden Hazard wẹ̀ 'yan kàì-kàin níbi tí Chelsea ti na Brighton ní 1-2

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eden Hazard gbá bọ́ọ̀lù kan sí àwọ̀n ó sì ṣe sábàbí ọ̀kan yókù nínú ìfẹsẹ̀swọnsẹ̀ tí Chelsea ti na Brighton ní pápá ìṣeré Amex Stadium.
Atamátàsé ilẹ̀ Belgium náà ló gbá bọ́ọ̀lù sí Pedro tó jẹ bọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ fún Chelsea ní ìṣẹ́jú mẹ́tàdínlógún sí ìgba tí wọ́n bẹ̀rẹ eré.
Lẹ́yìn náà ni Willian bá sá tẹ̀lé bọ́ọ̀lù tí Leon Balogun tó sì tarí rẹ̀ sí Hazard, ẹni tó sáré láti ìdajì pápá tó sì kọjá àwọn olùsọ́lé Brighton, kó tó gb;a bọ́ọ̀lù sáwọ̀ lẹ́yìn Mat Ryan.
Brighton, kò le ta pútú kí wọ́n tó lọ fún ìsimi ìdajì àsìkò.
Ṣùgbọ́n wọ́n ayò Brighton yàtọ̀ si lẹ́yìn ìgba tí wọ́n fi atamátàsé Romania, Florin Andone, sínú eré tó sì bá wọn pa àmì ayò kan ré ní ìṣẹ́jú mẹ́rìndínláàádọ́rin (66)
Pẹ̀lú èsì ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà Chelsea dúró sí ipò kẹẹ̀rin nígbà tí wà ní ipò kẹẹ̀tàlá.

Oríṣun àwòrán, EPA








