Oba Sunday Oyediran ṣàlàyé kíkún nípa ìṣẹ̀ṣe, ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn tí kò dí ará wọn lọ́wọ́- Onpetu

Àṣìṣe dokita lo pa Olori Funmilayo, kii ṣe nitori pé mi o ṣetutu iṣẹṣẹ kí ń to jọba- Oba Sunday Oyediran

Kò sí Ọba tí kìí ṣètùtù, ẹ̀jẹ̀ tí à ń tá sílẹ̀ ló yàtọ̀ síra wọn- Onpetu Ijeru

BBC Yoruba ṣabẹwo si ori ade Onpetu ti Ijeru ni ẹkun Ogbomọṣọ ni ipinlẹ Oyo ni guusu Iwọ oorun Naijiria.

Oba Sunday Oladapo Oyediran sọrọ ni kikun lori Iṣẹṣẹ, Igbagbọ ati Ẹsin.

Kabiesi mẹnuba iyatọ wọn ati ijọra wọn nipa fifi idi ẹ mulẹ pe ẹsin mẹtẹẹta mu itajẹsilẹ dani.

Esin Abalaye, Igbagbọ ati Musulumi ni o gbagbọ ninu itajẹsilẹ.

Oba Sunday Oyediran ni ẹsin to ba wu Oba ninu mẹtẹẹta lo le yan laayo lati maa ṣe ṣugbọn gbogbo ẹ naa lo n beere fun etutu siṣe, ọna ti koowa fi n ṣetutut rẹ lo kan yatọ sira wọn.

Nigba ti Kabiesi Onpetu n dahun ibeere BBC Yoruba lori idi ti ko ṣe ṣetutu ṣaaju ifọba jẹ, Oba ni oun ṣetutu ni ilana ẹsin ti oun faaye gba ni.

Kabiesi tun ṣo pe irọ pata nipe aiṣetutu abalaye lo jẹ ki Olori meji ku laafin oun.

Oba Sunday Oyediran ṣalaye pe aṣiṣe dokita lasiko ibimọ ṣaaju ki oun to jọba lo pa Olori Funmilayo.

Ati pe oun kii fẹ sọrọ nipa rẹ ki inu ọmọ ti Olori Funmilayo bi silẹ ma baa maa bajẹ.

Oba tun sọ nipa iku Olori Joy to wa lati abule Chibok nipinlẹ Borno to jẹ gambari pe ko ṣaisan ko to ku ṣugbọn ọlọjọ Olori Joy lo de laisko naa.

Ni ipari Kabiesi Onpetu ti Ijeru ni ẹwe kan ko le bọ lara igi ki Olorun ma mọ sii ni ọrọ ẹda nile aye.

O fi ayọ rẹ han ninu Jesu pe onigbagbọ tootọ ni oun ti oun si n ṣetutu ni ilana ti ẹsin oun faaye gba nigba gbogbo.

Oba ni etutu lọna ti oun mọ yii lo n bi eso alaafia ni ilu ti oun jọba le lori.