"Mo ké bòòsí tòò bí mo ṣe bí ìbejì, ti ọ̀kan jẹ́ àfín, tí ìkejì sì jẹ́ dúdú"

"Mo ké bòòsí tòò bí mo ṣe bí ìbejì, ti ọ̀kan jẹ́ àfín, tí ìkejì sì jẹ́ dúdú"

Gbogbo ọjọ kẹtala ọdọọdun ni awujọ agbaye ya sọtọ gẹgẹ bii ọjọ ilaraẹnilọyẹ nipa awọn Aafin.

Awọn aafin yii lo jẹ akanda ẹda kan, ti Ọlọrun da ya sọtọ nipa awọ ara wọn, ti Yoruba si ri wọn gẹgẹ bii orisa.

Oniruuru asa ni awọn eeyan maa n so mọ awọn Aafin, wọn ni wọn kii jẹ iyọ, wọn kii riran ni ọsan gangan ayafi ni alẹ tabi ninu okunkun.

Eyi to wa se pabambari ibẹ ni pe awọn kan gba pe orisun owo nla ni awọn Aafin jẹ nitori pe wọn maa n jẹ oogun owo.

Awọn ero yii si lo mu ki ọpọ eeyan maa dẹyẹ si awọn aafin yii, ti wọn si tun jẹ eeyan ọtọ ni awujọ.

Lasiko igbiyanju BBC Yoruba lati mọ ohun ti awọn Aafin yii n la kọja, la se alabapade ibeji kan, Taiwo ati Kehinde Olateju, ti isẹda mọ yatọ gedegede.

Idi ni pe Taiwo jẹ Aafin amọ ti Kehinde jẹ dudu.

Awọn mejeeji ati mama wọn si lo ba BBC Yoruba sọr lori ohun ti wọn la kọja nipa isẹlẹ yii ati ipenija ti Taiwo to jẹ Aafin n koju lawujọ.

“Ẹnikan ni ki wọn ge irun ori Taiwo wa, Ọlọrun lo yọ mi ti asiri ọrọ naa fi tu.”

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Mama Ibeji naa salaye bo se ri lara rẹ nigba to bi ibeji ti awọ wọn se ọtọọtọ.

Mama Olateju ni se ni oun pariwo nigba ti oun ri ọkan ninu awọn ibeji naa to jẹ Aafin.

O salaye pe aworan oyun, Scan, ti oun se ko fihan pe ọkan jẹ Aafin wa ninu awọn ibeji naa.

“Baba wọn ko tiẹ ka eyi si, o ni ọmọ to yẹ ki oun bi si oke okun lo wa sile, to si sọ ni Olatokunbo

Nigba tawọn naa n sọrọ awọn ibeji sọ ohun ti wọn la kọja ni kekere ati ni agba, paapaa Taiwo, to jẹ Aafin.

“Ẹnikan ni ki wọn ge irun ori Taiwo wa, Ọlọrun lo yọ mi ti asiri ọrọ naa fi tu.”