‘Bí ìjọba yóò bá dá ìpínlẹ̀ kan sílẹ̀, Ibadan ló gbọdọ̀ jẹ́’

‘Bí ìjọba yóò bá dá ìpínlẹ̀ kan sílẹ̀, Ibadan ló gbọdọ̀ jẹ́’

Aarẹ ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ Ibadan, Amofin Wole ajewole, ti sọ pe Ibadan lo tọ si lati jẹ ipinlẹ kẹtadinlogoji ni Naijiria.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC ni amofin Ajewole ti ṣalaye pe pẹlu bi ilu naa ṣe jẹ ibi ti ọpọ eniyan n gbe, to si tun ni ijọba ibilẹ mọkanla, ati awọn akọṣẹmọṣẹ to pọ julọ nilẹ Africa, o yẹ ki ijọba apapọ buwọlu si sọ ọ di ipinlẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe ilu Ibadan nikan ko ida mẹtalelaadọta ninu gbogbo ipinlẹ Oyo.

Ẹwẹ, o ni gbogbo nnkan to yẹ ni awọn to jẹ ọmọ Ibadan ati awọn oludari wọn ti ṣe lati mu ki ala naa o wa si imuṣẹ.