Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti sọ pe awọn agunbanirọ obinrin le maa wọ sikẹẹti ti ẹsin wọn ba tako ṣokoto wiwọ
Idajọ yii lo waye lẹyin ti agunabinrọ meji kan pe ẹjọ tako ajọ NYSC, lẹyin to kọ lati fun wọn ni iwe ẹri nitori wọn kọ lati wọ ṣokoto
Lọ soju ojo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
_____________
Ajọ eleto abo Amotekun ipinlẹ Osun ti fẹsun kan ọmọ ogun kan, Opejobi Fiyinfoluwa
Pe o ṣekupa Peter Samuel Tope to jẹ oṣiṣẹ Amotekun niluu Ijebu-Jesa
Wọn ni ṣe ni afurasi naa la nnkan mọ oloogbe ọhun lori lati ori ọkada, to si n na a fun nnkan bii ogun iṣẹju
Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ osun ti fidi iroyin naa mulẹ ati pe iwadii ti bẹrẹ
_____________
Lorilẹede DR Congo
O kere tan, ogoji olujọsin lo ti di oloogbe lẹyin ikọlu awọn alakatakiti kan lagbegbe Komanda
A gbọ pe pupọ ninu awọn oloogbe naa lo n ṣe iṣọ oru lọwọ lasiko ikọlu ọhun
Ọmọde mẹsan lo wa lara wọn to ba iṣẹlẹ naa lọ