Kàyééfì! ‘Kọ̀rọ̀ Afọ́jú’ ìletò àwọn afọ́jú níbi tí ọmọ afọ́jú kò ti lè jogún òbí rẹ̀

Kàyééfì! ‘Kọ̀rọ̀ Afọ́jú’ ìletò àwọn afọ́jú níbi tí ọmọ afọ́jú kò ti lè jogún òbí rẹ̀

Ileto kan n bẹ nilu Ilọrin ti wọn n pe ni ‘Kọrọ Afọju’ ni ilu Ilọrin.

Awọn afọju lo ni ileto yii awọn naa ni wọn n gbe ibẹ ti wọn si n jọba lori ileto naa.

Gbogbo ọjọ Abamẹta, Satide ni awọn afọju gbogbo ni agbegbe naa maa n wa fun ipade ni kọrọ afọju yii.

Gẹgẹbi alaye ti wọn ṣe fun BBC News Yoruba, nnkan bii agogo mẹsan an owurọ ni ipade wọn naa maa n bẹrẹ titi di agogo mọkanla abọ

Awọn kayefi to rọ mọ ileto ‘Kọrọ Afọju’ yii

Lara awọn kayefi to wa ni ileto yii ni pe bi afọju kankan ba kọ ile ni ileto naa, ọmọ rẹ kankan ko lẹtọ lati jogun ile yii ayafi afọju miran bii tirẹ.

Bi afọju kankan ba ku ni ileto naa, ayafi ki ọmọ rẹ lọ gba ile si ita ni, nitori pe iru ọmọ bẹẹ to ba jẹ ọmọ ti oju rẹ la perepere, ko le e gbe ninu ileto naa mọ lẹyin ipapoda awọn obi rẹ.