You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo òyìnbó tó ń fi èdè Yorùbá kọrin ju ọmọ Yorùbá míì lọ
Lóde òní, ó máa ń jẹ́ ohun ìwúrí lọ́pọ̀lọpọ̀ tí a bá rí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn tó bá ń fi èdè Yorùbá dá àwọn àrà lọ́kan-ò-jọ̀kan.
Arábìnrin kan rèé tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Malta ní ilẹ̀ Yúróòpù tó ń fi èdè Yorùbá dá àrà nípasẹ̀ orin kíkọ.
Orin ìyìnrere ni Omolara Familua tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Omolara music yàn láàyò èyí tó máa ń kọ pẹ̀lú oríṣiríṣi èdè tí èdè Yorùbá sì wà lára àwọn èdè tó yàn láàyò.
Omolara ní òun máa ń kọ orin ní èdè Yorùbá, Igbo, Hausa, Gẹ̀ẹ́sì, Maltese, Italian, Spanish àti Faransé.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, ọkọ Omolara, Oluwamayowa Familua ní lẹ́yìn tí àwọn ṣe ìgbéyàwó lọ́dún 2005 ni Omolara bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìfẹ́ hàn sí èdè Yorùbá.
Oluwamayowa ní látara ìfẹ́ tí Omolara ní sí orin ló máa ń bèèrè ìtúmọ àwọn orin tí òun bá ń gbọ́ léde Yorùbá tó sì ti ara bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí láti máa kọ orin ní èdè Yorùbá.
Ó ṣàlàyé pé Omolara ti máa ń kọrin pẹ̀lú àwọn èdè mìíràn láti ọjọ́ pípẹ́ kó tó di wí pé ó tún nú èdè Yorùbá mọ́ ọn.
Ó fi kun pé lẹ́yìn tí àwọn ṣe ìgbéyàwọ tán ni Omolara lọ ra àwọn ìwé àtúnmọ̀ èdè sí Yorùbá láti túnbọ̀ kọ́ nípa èdè Yorùbá jinlẹ̀ si.
Omolara ṣàlàyé ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni kíkọ orin pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè jẹ́ fún òun.
Oluwamayowa rọ àwọn òbí àti alágbàtọ́ láti máa fi èdè abínibí kọ́ àwọn ọmọ nítorí èdè tí èèyàn kò bá ti máa fi kọ́ àwọn ọmọ máa ń parun ni.