You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tí mo bá di gómìnà, ìpínlẹ̀ Osun ni àkọ́kọ́ ní Naijiria ti yóò máá pèsè iná ìjọba fúnra rẹ̀ - Goke Omigbodun
Oludije sipo gomina nipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu SDP, Goke Omigbodun, ti sọ pe oun lo kawe julọ ninu gbogbo awọn to n dije du ipo gomina nipinlẹ naa.
Omigbodun lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
Omigbodun, to jẹ oludasilẹ oniruru ile ẹkọ nipinlẹ Osun ni ,o da oun loju pe oun gan ni yoo gbegba oroke ninu eto idibo naa.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, oriṣiriṣi eto loun ti la kalẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Osun lati maye dẹrun wọn.
Oludije naa tun sọ pe oun yoo san awọn gbese ti awọn ijọba to ti jẹ ṣaaju ni ipinlẹ naa sẹyin.
O tẹsiwaju pe ijọba oun yoo ri daju pe ipinlẹ Osun ni yoo jẹ ipinlẹ akọkọ ni Naijiria ti yoo maa pese ina ijọba funra rẹ.
O fi kun pe oun yoo tun ṣe idasilẹ eto “Agbada Oye” eyii ti yoo maa pese iṣẹ fun awọn araalu nipa eto ayelujara bii ti Silicon Valley, to wa nipinlẹ Carlifornia, l’Amẹrika.