You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Adajọ Olabisi Ogunkanmi ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku nilu Ibadan,ti paṣẹ pe
ki wọn fi Olori Ọọni Ile-Ifẹ tẹlẹ, Naomi Silekunola ati Oriyomi Hamzat to jẹ alakoso ileeṣẹ redio Agidigbo pamọ sọgba ẹwọn.
Eyi ko ṣẹyin apejẹ ti Naomi ṣagbatẹru rẹ n'Ibadan nibi tọmọde marundinlogoji ti ku
Nigba wo n'igbẹjọ yoo tun waye?
Lo soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ.
''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Mi o kabamọọ wi pe mo yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro
Aarẹ Bola Tinubu lo sọ bẹẹ nigba to n dahaun ibeere awọn akọroyin lalẹ ọjọ Aje
Koda Tinubu tun sọ pe oun ko ni wẹyin wo lori abadofin owo ori tuntun to wa niwaju ile aṣofin agba l'Abuja
Ẹkunrere wa lori ikanni BBC Yoruba
''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Eṣu laalu ogiri oko, o bẹlẹkun sunkun kẹrẹ o bẹlẹkun
Ṣebi kristẹni ni ọ, nigba wo lo bẹrẹ si bọ Esu?
Emi ma kọ, oni lawọn ọmọlẹyin Esu n ṣe ayajọ ọjọ Ẹṣu niluu Akure
Ti ẹ ba fẹ mọ bi ọdun Esu ṣe lọ lonii niluu Akure