You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tina Ogundoyin, màmá olórí ilé aṣòfin Oyo jáde láyé
Iya to bí olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, Asofin Adebo Ogundoyin ti jade laye.
Oloye Justina Iyabo Ogundoyin, ẹni to jẹ iyawo kẹrin fun gbajumo oniṣowo ọmọ Eruwa, Oloye Adeseun Ogundoyin, lo jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgọta.
Oloogbe naa jade laye lasiko aisan ranpẹ.
Olori ile asofin ipinlẹ Oyo, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin sapejuwe ipapoda iya rẹ gẹgẹ ohun to ba lojiji, to si tun ko irẹwẹsi ọkan ba pupọ.
"Iya rere ni iya mi si gbogbo wa, ko si ọrọ kan tí mo le fi sapejuwe bi iku rẹ ṣe rí lọkan mi"
"Iya mi ti da gbere fun ile aye. Eyi dun mi, ko si nnkan miiran to dun emi ati mọlẹbi to eyi.
"Iya rere ni iya mi si gbogbo wa. Ko si ọrọ kan tí mo le fi sapejuwe bi o ṣe rí lọkan mi bayìí"
Adebo Ogundoyin wa gba ladura pe ki Ọlọrun ṣe ikẹ iya oun, ko si da bobo awọn mọlẹbi yooku to wa laye.
Yeye Justina Iyabo Ogundoyin ni iyaloja fun gbogbo Ibarapa mejeeje nipinlẹ Oyo.