You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ejigbo, ìlú ti gbogbo ìdílé ti n sọ èdè Faranse bótilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Yorùbá ni wọ́n
Ọkan lara awọn ilu to gbajumọ nilẹ Yoruba, paapaa nipinlẹ Osun, ni Ejigbo.
Ijọba ibilẹ ni ilu yii wa ni ijọba ibilẹ Ejigbo, oun si ni olu-ilu fun ijọba ibilẹ naa.
Ohun kan to gbajumọ, to si ma n jẹ iyalẹnu fun gbogbo eeyan ti kii ṣe ọmọ ilu na ni pe, ko fẹ ẹ si idile tabi agboole kan ti ko sọ ede Faranse.
Ede Faranse kii ṣe ede ti a n sọ ni orilẹede Naijiria rara, awọn eeyan ma n kọ ọ ni boya nile ẹkọ tabi gbigbe ni awọn orilẹede ti wọn ti n sọ ede naa bii France, Ivory Coast, Benin Republic, C,ote d'ivoire ati awọn mii.
Ba wo wa a ni ti awọn eeyan ilu Ejigbo ṣe jẹ, to fi jẹ pe ede Faranse ti di ede abinibi wọn?
Eyi lo mu ki BBC News Yoruba rinrinajo lọ si ilu naa, lati ṣe iwadii bi ọrọ ṣe ri bẹẹ.
Owagboye Teslim Abefe, Ọsọlọ ilẹ Ejigbo, sọ fun BBC pe, lati ayebaye ni ilu Ejigbo ti ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu ilu Abidjan, tii ṣe ilu to tobi julọ ni orilẹede Ivory Coast.
O ṣalaye pe, ni igba atijọ ni awọn babanla wọn rinrinajo kuro ni ilu Ejigbo lati ṣe ọrọ aje lọ si awọn ilu miran.
"Awọn kan lara wọn duro si Togo, Ghana, amọ Abidjan ni wọn pọ si ju.
"Abidjan ni ilu ti ọmọ Ejigbo pọ si julọ."
Awọn eeyan mii ti a tun ba sọrọ ṣalaye pe, lati kekere ti wọn ba ti bi ọmọ niluu Ejigbo, ni awọn ẹbi rẹ yoo ti mu u lọ si Abidjan.
Nibẹ ni ọmọ naa yoo ti lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ tabi ti girama. Lẹyin naa, wọn le mu u pada sile tabi ko kuku tẹso si ilu Abidjan.
Bayii ni awọn eeyan Ejigbo ṣe n gbe igbeaye wọn titi di oni, eyi to sọ wọn di ẹni to n sọ ede Faranse yatọ si ede Yoruba ati Gẹẹsi.
Ọsọlọ ilẹ Ejigbo tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, ilu Ejigbo lo so ọpọ ilu ni Naijiria pọ mọ ilu Abidjan.
"Idi ni pe, Ejigbo nikan ni wọn ti ma n ri ọkọ ti yoo gbe wọn taara de Abidjan lai si iduro tabi wiwọ ọkọ kelekele."