Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba kò ní gba owó orí àwọn oúnjẹ́ àtàwọn nǹkan mìí láti dín ìrorà ọrọ̀ ajé kù?

Ileeṣẹ aarẹ ti sọrọ lori iroyin kan to n lọ pe, ijọba ti da gbigba owo ori lori awọn ounjẹ ati oogun to n wọle lati ilẹ okeere.

Ṣaaju ni awọn ile iṣẹ iroyin kan, ati awọn eeyan mii lori ayelujara n kede pe Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu u pe ki ajọ aṣọbode o ma gba owo ori lọwọ awọn olokoowo to n ko ounjẹ, oogun ati awọn eroja koṣeemani yooku, fun oṣu mẹfa gbako.

Lara awọn nnkan ti wọn tun kọ sinu awọn iwe naa ni pe ijọba ko ni gba owo ori lori awọn nnkan bi fatalaisa, ounjẹ adiyẹ, iyẹfun ati awọn ounjẹ onihoro.

Iroyin naa sọ pe oṣu mẹfa akọkọ naa ni ijọba fẹ ẹ fi mu adinku ba irora ọrọ aje to n ba awọn araalu finra.

Kini ijọba sọ lori iroyin naa?

Ṣugbọn ninu atẹjade ti oludamọran fun aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita l’Ọjọbọ, sọ pe iwe akọsilẹ meji ti wọn n pin kiri naa, ko wa a lati ileeṣẹ aarẹ.

Ọgbẹni Onanuga ṣalaye pe lootọ ni awọn iwe naa jẹ akọsilẹ awọn eto kan to n lọ lọwọ l’abẹlẹ, o ni ṣugbọn wọn ko ti i ni ontẹ gẹgẹ bi awọn eeyan naa ṣe n sọ.

“Akọsilẹ nipa awọn igbesẹ ti ijọba n gbero lati gbe ni wọn lootọ, ṣugbọn wọn o ṣi la oriṣiriṣi ipele kọja lọdọ awọn alaṣẹ ijọba ka to o mọ boya yoo ṣiṣẹ tabi bẹẹkọ.”

Ẹwẹ, Bayo Onanuga ṣalaye pe minisita fun eto ọrọ aje, Wale Edun, ti sọ pe wọn o jẹ ki araalu mọ iha ti ijọba kọ si awọn ilana ọhun, lẹyin ti ayẹwo ati ibuwọlu ba ti waye.