You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Arákùnrin kòkúmọ́ tó móríbọ́ nínú ìjambá bàlúù lóṣù kẹ́fà kérora pé lóòótọ́ òun móríbọ́ ṣùgbọ́n bí ẹdun arinlẹ̀ lòun wà báyìí
Baluu naa n morile ilu London nigba to ja lulẹ ni Ahmedabad, ṣugbọn Viswashkumar Ramesh nikan lo fi ẹsẹ ara rẹ rin kuro nibi ti baluu naa ja si, eleyii to jẹ iyanu nla fun ọpọlọpọ eeyan jakejado agbaye.
Arakunrin naa ni 'iyanu' nla lo jẹ pe oun moribọ ninu ijamba naa. Amọṣa ninu ifọrọwerọ to ṣe bayii, o ni gbogbo nnkan loun le sọ̀ pe oun ti padanu pẹlu bo ṣe jẹ wi pe aburo oun ọkunrin ti orukọ rẹ n jẹ Ajay ku sinu ijamba baluu.
Lati igba to ti pada si ile rẹ ni ilu Leicester ni orilẹede Gẹẹsi, Ọgbẹni Ramesh kii ye ranti iṣẹlẹ naa to si n da ọkan rẹ laamu gidigidi, bẹẹni ko lee ba iyawo rẹ tabi ọmọ rẹ ọkunrin ọmọ ọdun mẹrin sọ ohunkohun.