You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò lè sí àlááfìà láàrín èmi àti Atiku lórí ìbò ààrẹ - Wike
Bi idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria ṣe n sun mọ etile, eyi ti yoo waye ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu keji, gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti sọ pe ko sọrọ mọ laarin oun ati oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar lori atilẹyin fun idibo aarẹ to n bọ lọna.
Wike ṣalaye ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ nilu Port Harcourt lọjọbọ pe, nibi ti ọrọ de duro bayii, ko le e si ọrọ binukonu kankan mọ laarin oun ati Atiku ni iwọnba asiko to ku si ọjọ idibo apapọ naa.
Gomina Wike ni oun ko ni ọrọ tabi arọwa kankan lori ipade to waye laarin oun ati oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu lọjọru ṣaaju ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ naa.
Igbagbọ Atiku ni pe yoo bori ibo aarẹ, emi ko ṣetan lati ba ẹnikẹni joko sọrọ mọ - Wike
“O ti bọ sori! A ti sọ ṣaaju asiko yii pe ko si nnkan ti ẹnikẹni le e ṣe lori eyi mọ.
Igbagbọ wọn ni pe wọn le bori ninu eto idibo naa. Emi ko ṣetan lati ba ẹnikẹni joko sọrọ mọ o!”
Ede-aiyede waye laarin Wike ati Atiku lẹyin ipade idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP to waye loṣu karun un ọdun 2022.
Eyi si lo fa idasilẹ igbimọ awọn gomina marun to n ja fun dida ipo aarẹ pada si ẹkun gusu Naijiria, ti wọn pe ni G5.
Awọn gomina maraarun naa ni gomina Samuel Ortom (Benue), Seyi Makinde (Ọyọ), Okezie Ikpeazu (Abia) ati Ifeanyi Ugwuanyi (Enugu).
Koko ohun ti awọn gomina maraaun naa n beere fun bayii ni pe ki alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorcha Ayu fipo silẹ nitori pe ko tọna ki oludije aarẹ ati aarẹ ẹgbẹ oṣelu kan wa lati ẹkun kan naa.
Amọṣa Wike ko ṣalaye oludije ti oun atawọn akẹgbẹ rẹ mẹrin yoku n to si lẹyin fun eto idibo aarẹ to n bọ naa.