Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Bi awujọ agbaye se n ṣami ayajọ ounjẹ lonii
Igbe ebi ati ọwọn gogo ounjẹ lawọn ọmọ Naijiria bọnu, bi ẹkun omi ati ọgbẹlẹ ṣe n ba ere oko jẹ
Koda, ọpọ ọmọde ni wọn sọ pe ko ri ounjẹ asaraloore jẹ mọ
Ti awọn agbẹ ọlọgbin agbado, atawọn ounjẹ onikoro mii n bomi loju nitori nnkan ọgbin wọn ti ko yọmọ
Ki lo wa fa a to fi ri bẹẹ?
Kan si oju opo bbc.com/Yoruba fẹkunrẹrẹ nnkan tawọn onimọ wi
O ma ṣe o, ọgọrun-un eeyan ku, awọn aadọta mii tun farapa
Nibi iṣẹlẹ ijamba ina to waye nigba ti ọkọ agbepo kan gbina ni ipinlẹ Jigawa
Adari ẹṣọ oju popo nipinlẹ Jigawa, Aishatu Saadu sọ fun BBC pe
Lasiko ti ọkọ agbepo naa n gbiyanju lati ya fọkọ nla miiran ni epo rẹ yi danu
To si gbina nigba tawọn araalu n gbọn epo naa
Ijọba apapọ ti kede lati pin owo tiriliọnu mẹsan-an naira fun Ogun miliọnu eeyan ti iṣẹ ati oṣi n ba finra
Ṣe loootọ, bawo wa ni maa se gba ninu owo naa?
Kan si oju opo bbc.com/Yoruba fun ẹkunrẹrẹ bo ṣe le ri owo tirẹ gba
